O. Daf 27:4-9

O. Daf 27:4-9 YBCV

Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ Oluwa, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile Oluwa li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà Oluwa, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tempili rẹ̀. Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata. Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa. Gbọ́, Oluwa, nigbati mo ba fi ohùn mi pè: ṣanu fun mi pẹlu, ki o si da mi li ohùn. Nigbati o wipe, Ẹ ma wa oju mi; ọkàn mi wi fun ọ pe, Oju rẹ, Oluwa, li emi o ma wá. Máṣe pa oju rẹ mọ́ kuro lọdọ mi; máṣe fi ibinu ṣa iranṣẹ rẹ tì: iwọ li o ti nṣe iranlọwọ mi; má fi mi silẹ, bẹ̃ni ki o máṣe kọ̀ mi, Ọlọrun igbala mi.