Mo fẹ́ ọ, OLúWA, agbára mi.
OLúWA ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;
Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.
Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.
Mo ké pe OLúWA, ẹni tí ìyìn yẹ fún,
a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
Ìrora ikú yí mi kà,
àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
Okùn isà òkú yí mi ká,
ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.
Nínú ìpọ́njú mo ké pe OLúWA;
Mo sọkún sí OLúWA mi fún ìrànlọ́wọ́.
Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;
ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.
Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì,
ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí;
wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú.
Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá;
Iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá,
ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀.
Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá;
àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
Ó gun orí kérúbù, ó sì fò;
ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́.
Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká
kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run.
Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ
pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná
OLúWA sán àrá láti ọ̀run wá;
Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná.
Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká,
ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú.
A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn Òkun hàn,
a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé
nípa ìbáwí rẹ, OLúWA,
nípa fífún èémí ihò imú rẹ.
Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú;
Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn.
Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára,
láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi.
Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi;
ṣùgbọ́n OLúWA ni alátìlẹ́yìn mi.
Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá;
Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi.
OLúWA ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi
Nítorí mo ti pa ọ̀nà OLúWA mọ́;
èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi
Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;
èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀.
Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀;
mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.
OLúWA san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;
gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.