O. Daf 18:1-24

O. Daf 18:1-24 Bibeli Mimọ (YBCV)

EMI o fẹ ọ, Oluwa, agbara mi. Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi. Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi. Irora ikú yi mi ka, ati iṣàn-omi awọn enia buburu dẹ̀ruba mi. Irora ipò okú yi mi kakiri: ikẹkun ikú dì mi mu. Ninu ìṣẹ́ mi emi kepè Oluwa, emi si sọkun pe Ọlọrun mi: o gbohùn mi lati inu tempili rẹ̀ wá, ẹkún mi si wá si iwaju rẹ̀, ani si eti rẹ̀. Nigbana ni ilẹ mì, o si wariri: ipilẹ òke pẹlu ṣidi, o si mì, nitoriti o binu. Ẹ̃fin ti iho imu rẹ̀ jade, ati iná lati ẹnu rẹ̀ wá njonirun: ẹyín gbiná nipasẹ rẹ̀. O tẹri ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ wá: òkunkun si mbẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀. O si gùn ori kerubu o si fò: nitõtọ, o nra lori iyẹ-apa afẹ́fẹ́. O fi òkunkun ṣe ibi ìkọkọ rẹ̀: ani agọ́ rẹ̀ yi i ka kiri; omi dudu, ati awọsanma oju-ọrun ṣiṣu dudu. Nipa imọlẹ iwaju rẹ̀, awọsanma ṣiṣu dùdu rẹ̀ kọja lọ, yinyín ati ẹyín iná. Oluwa sán ãra pẹlu li ọrun, Ọga-ogo si fọ̀ ohùn rẹ̀: yinyín ati ẹyín iná! Lõtọ, o rán ọfa rẹ̀ jade, o si tú wọn ká: ọ̀pọlọpọ manamana li o si fi ṣẹ́ wọn tũtu. Nigbana li awowò omi odò hàn, a si ri ipilẹ aiye nipa ibawi rẹ, Oluwa, nipa fifun ẽmi iho imu rẹ. O ranṣẹ́ lati òke wá, o mu mi, o fà mi jade wá lati inu omi nla. O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, ati lọwọ awọn ti o korira mi; nitori nwọn li agbara jù mi lọ. Nwọn dojukọ mi li ọjọ ipọnju mi: ṣugbọn Oluwa li alafẹhintì mi. O mu mi jade pẹlu sinu ibi nla; o gbà mi nitori inu rẹ̀ dùn si mi. Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi; gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li o san a fun mi. Nitori mo ti nkiye si ọ̀na Oluwa, emi kò fi ìka yà kuro lọdọ Ọlọrun mi. Nitori pe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi, bẹ̃li emi kò si yẹ̀ ofin rẹ̀ kuro lọdọ mi. Emi si duro ṣinṣin pẹlu rẹ̀, emi si paramọ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi. Nitorina li Oluwa ṣe san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li oju rẹ̀.

O. Daf 18:1-24 Yoruba Bible (YCE)

Mo fẹ́ràn rẹ, OLUWA, agbára mi. OLUWA ni àpáta mi, ibi ààbò mi, ati olùgbàlà mi; Ọlọrun mi, àpáta mi, ninu ẹni tí ààbò mi wà. Òun ni asà mi, ìwo ìgbàlà mi ati ibi ìsásí mi. Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi. Ikú wé mọ́ mi bí okùn, ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi rírú omi. Isà òkú yí mi ká, tàkúté ikú sì dojú kọ mí. Ninu ìpọ́njú mi mo ké pe OLUWA, Ọlọrun mi ni mo ké pè. Ó gbọ́ ohùn mi láti inú ilé mímọ́ rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí igbe mi. Ilẹ̀ ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè mì jìgìjìgì; wọ́n wárìrì nítorí tí ó bínú. Èéfín ṣẹ́ jáde láti ihò imú rẹ̀, iná ajónirun yọ jáde láti ẹnu rẹ̀; ẹ̀yinná sì ń jò bùlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá. Ó dẹ ojú ọ̀run sílẹ̀, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá, ìkùukùu tó ṣókùnkùn biribiri sì wà lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó gun orí Kerubu, ó sì fò, ó fò lọ sókè lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́. Ó fi òkùnkùn bora bí aṣọ, ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn, tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí. Ninu ìmọ́lẹ̀ níwájú rẹ, ẹ̀yinná ati yìnyín ń fọ́n jáde, láti inú ìkùukùu. OLUWA sán ààrá láti ọ̀run, Ọ̀gá Ògo fọhùn, òjò dídì ati ẹ̀yinná sì fọ́n jáde. Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká, ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká. Nígbà náà ni ìsàlẹ̀ òkun hàn ketekete, ìpìlẹ̀ ayé sì fojú hàn gbangba nítorí ìbáwí rẹ, OLUWA, ati nítorí agbára èémí ihò imú rẹ. Ó nawọ́ láti òkè wá, ó sì dì mí mú, ó fà mí jáde láti inú ibú omi. Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi tí ó lágbára, ati lọ́wọ́ àwọn tí ó kórìíra mi; nítorí wọ́n lágbára jù mí lọ. Wọ́n gbógun tì mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, ṣugbọn OLUWA ni aláfẹ̀yìntì mi. Ó mú mi jáde wá síbi tí ó láàyè, ó yọ mí jáde nítorí tí inú rẹ̀ dùn sí mi. OLUWA ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi, bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ ni ó ṣe pín mi lérè. Nítorí tí mo ti pa ọ̀nà OLUWA mọ́, n kò ṣe ibi nípa yíyà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi. Nítorí pé gbogbo òfin rẹ̀ ni mo tẹ̀lé, n kò sì yà kúrò ninu ìlànà rẹ̀. Mo wà ní àìlẹ́bi níwájú rẹ̀, mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; ati gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ṣe mọ́ lójú rẹ̀.

O. Daf 18:1-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mo fẹ́ ọ, OLúWA, agbára mi. OLúWA ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi; Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi. Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi. Mo ké pe OLúWA, ẹni tí ìyìn yẹ fún, a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi. Ìrora ikú yí mi kà, àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí. Okùn isà òkú yí mi ká, ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí. Nínú ìpọ́njú mo ké pe OLúWA; Mo sọkún sí OLúWA mi fún ìrànlọ́wọ́. Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi; ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀. Ayé wárìrì, ó sì mì tìtì, ìpìlẹ̀ àwọn òkè gíga sì ṣídìí; wọ́n wárìrì nítorí tí ó ń bínú. Èéfín ti ihò imú rẹ̀ jáde wá; Iná ajónirun ti ẹnu rẹ̀ jáde wá, ẹ̀yin iná bú jáde láti inú rẹ̀. Ó pín àwọn ọ̀run, Ó sì jáde wá; àwọsánmọ̀ dúdú sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó gun orí kérúbù, ó sì fò; ó ń rábàbà lórí ìyẹ́ apá afẹ́fẹ́. Ó fi òkùnkùn ṣe ibojì rẹ̀, ó fi ṣe ìbòrí yí ara rẹ̀ ká kurukuru òjò dúdú ní ojú ọ̀run. Nípa ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀, àwọsánmọ̀ ṣíṣú dudu rẹ kọjá lọ pẹ̀lú yìnyín àti ẹ̀yín iná OLúWA sán àrá láti ọ̀run wá; Ọ̀gá-ògo sì fọ ohun rẹ̀; yìnyín àti ẹ̀yin iná. Ó ta àwọn ọfà rẹ̀, ó sì tú àwọn ọ̀tá náà ká, ọfà mọ̀nàmọ́ná ńlá sì dà wọ́n rú. A sì fi ìsàlẹ̀ àwọn Òkun hàn, a sì rí àwọn ìpìlẹ̀ ayé nípa ìbáwí rẹ, OLúWA, nípa fífún èémí ihò imú rẹ. Ó sọ̀kalẹ̀ láti ibi gíga, ó sì dì mímú; Ó fà mí jáde láti inú omi jíjìn. Ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá mi alágbára, láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá, ti ó lágbára jù fún mi. Wọ́n dojúkọ mí ní ọjọ́ ìpọ́njú mi; ṣùgbọ́n OLúWA ni alátìlẹ́yìn mi. Ó mú mi jáde wá sínú ibi ńlá; Ó gbà mí nítorí tí ó ní inú dídùn sí mi. OLúWA ti hùwà sí mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi, ó ti fi èrè fún mi Nítorí mo ti pa ọ̀nà OLúWA mọ́; èmi kò ṣe búburú nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi Gbogbo òfin rẹ̀ ni ó wà níwájú mi; èmi kò sì yípadà kúrò nínú ìlànà rẹ̀. Mo ti jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú rẹ̀; mo sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. OLúWA san ẹ̀san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi; gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi níwájú rẹ̀.

O. Daf 18:1-24

O. Daf 18:1-24 YBCVO. Daf 18:1-24 YBCV