Saamu 149:6-9

Saamu 149:6-9 YCB

Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn. Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè, àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn, Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ irin de àwọn ọlọ́lá wọn. Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.