O. Daf 149:6-9
O. Daf 149:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki iyìn Ọlọrun ki o wà li ẹnu wọn, ati idà oloju meji li ọwọ wọn; Lati san ẹsan lara awọn keferi, ati ijiya lara awọn enia. Lati fi ẹ̀wọn dè awọn ọba wọn, ati lati fi ṣẹkẹṣẹkẹ irin dè awọn ọlọ̀tọ wọn; Lati ṣe idajọ wọn, ti a ti kọwe rẹ̀, ọlá yi ni gbogbo enia mimọ́ rẹ̀ ni. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.
O. Daf 149:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Kí wọn máa fi ohùn wọn yin Ọlọrun; kí idà olójú meji sì wà ní ọwọ́ wọn, láti gbẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ati láti jẹ àwọn eniyan wọn níyà; láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba orílẹ̀-èdè mìíràn, ati láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ de àwọn ọlọ́lá wọn; láti ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀. Ògo gbogbo àwọn olódodo nìyí.
O. Daf 149:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn. Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè, àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn, Láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn àti láti fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ irin de àwọn ọlọ́lá wọn. Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀.