Saamu 12:1-8

Saamu 12:1-8 YCB

Ràn wá lọ́wọ́, OLúWA, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́; Olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn. Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀; ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn. Kí OLúWA kí ó gé ètè èké wọn àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu tí ó wí pé, “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa; àwa ní ètè wa: Ta ni ọ̀gá wa?” “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní, Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni OLúWA wí. “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.” Ọ̀rọ̀ OLúWA sì jẹ aláìlábùkù, gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀, tí a sọ di mímọ́ nígbà méje. OLúWA, ìwọ yóò pa wá mọ́ kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé. Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.