O. Daf 12:1-8
O. Daf 12:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
GBÀ-NI Oluwa; nitori awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun dasẹ̀; nitori awọn olõtọ dasẹ̀ kuro ninu awọn ọmọ enia. Olukuluku wọn mba ẹnikeji rẹ̀ sọ asan; ète ipọnni ati ọkàn meji ni nwọn fi nsọ. Oluwa yio ké gbogbo ète ipọnni kuro, ati ahọn ti nsọ̀rọ ohun nla. Ti o wipe, Ahọn wa li awa o fi ṣẹgun; ète wa ni ti wa: tani iṣe oluwa wa? Nitori inira awọn talaka, nitori imi-ẹ̀dun awọn alaini, Oluwa wipe, nigbayi li emi o dide; emi o si yọ ọ si ibi ailewu kuro lọwọ ẹniti nfẹ̀ si i. Ọ̀rọ Oluwa, ọ̀rọ funfun ni, bi fadaka ti a yọ́ ni ileru erupẹ, ti a dà ni igba meje. Iwọ o pa wọn mọ́, Oluwa, iwọ o pa olukuluku wọn mọ́ kuro lọwọ iran yi lailai. Awọn enia buburu nrìn ni iha gbogbo, nigbati a ba gbé awọn enia-kenia leke.
O. Daf 12:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ràn wá lọ́wọ́, OLúWA, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́; Olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn. Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀; ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn. Kí OLúWA kí ó gé ètè èké wọn àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu tí ó wí pé, “Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa; àwa ní ètè wa: Ta ni ọ̀gá wa?” “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní, Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni OLúWA wí. “Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.” Ọ̀rọ̀ OLúWA sì jẹ aláìlábùkù, gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀, tí a sọ di mímọ́ nígbà méje. OLúWA, ìwọ yóò pa wá mọ́ kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé. Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.
O. Daf 12:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Gbani, OLUWA; nítorí àwọn olódodo kò sí mọ́; àwọn olóòótọ́ ti pòórá láàrin àwọn ọmọ eniyan. Olukuluku ń purọ́ fún ẹnìkejì rẹ̀; ọ̀rọ̀ ìpọ́nni èké ati ẹ̀tàn ni wọ́n ń bá ara wọn sọ. Kí OLUWA pa gbogbo àwọn tí ń fi èké pọ́nni run, ati àwọn tí ń fọ́nnu, àwọn tí ń wí pé, “Ẹnu wa yìí ni a óo fi ṣẹgun, àwa la ni ẹnu wa; ta ni ó lè mú wa?” OLUWA wí pé, “Nítorí ìnira àwọn aláìṣẹ̀, ati nítorí ìkérora àwọn tí à ń pọ́n lójú, n óo dìde nisinsinyii, n óo sì dáàbò bò wọ́n bí ọkàn wọn ti ń fẹ́.” Ìlérí tó dájú ni ìlérí OLUWA, ó dàbí fadaka tí a yọ́ ninu iná ìléru amọ̀, tí a dà ninu iná nígbà meje. Dáàbò bò wá, OLUWA, pa wá mọ́ laelae kúrò lọ́wọ́ irú àwọn eniyan báwọ̀nyí. Àwọn eniyan burúkú ń yan kiri, níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ ibi.