Saamu 119:81-96

Saamu 119:81-96 YCB

Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ, ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ. Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ; èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín, èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ. Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí? Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi, tí ó lòdì sí òfin rẹ. Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé: ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí. Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé, ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ. Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ, èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́. OLúWA Ọ̀rọ̀ rẹ, OLúWA, títí láé ni; ó dúró ṣinṣin ní ọ̀run Òtítọ́ rẹ̀ ń lọ dé gbogbo ìran dé ìran; ìwọ ti dá ayé, ó sì dúró ṣinṣin. Òfin rẹ dúró di òní nítorí ohun gbogbo ń sìn ọ́. Bí òfin rẹ̀ kò bá jẹ́ dídùn inú mi, èmi ìbá ti ṣègbé nínú ìpọ́njú mi. Èmi kì yóò gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ láé, nítorí nípa wọn ni ìwọ ti pa ayé mi mọ́ Gbà mí, nítorí èmi jẹ́ tìrẹ èmi ti wá ẹ̀kọ́ rẹ. Àwọn ẹni búburú dúró láti pa mí run, ṣùgbọ́n èmi yóò kíyèsi ẹ̀rí rẹ. Sí ohun pípé gbogbo èmi ti rí òpin; ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ aláìlópin ni.