ORIN DAFIDI 119:81-96

ORIN DAFIDI 119:81-96 YCE

Mo wá ìgbàlà rẹ títí, àárẹ̀ mú ọkàn mi; ṣugbọn mo ní ìrètí ninu ọ̀rọ̀ rẹ. Mo fojú sọ́nà títí, agara dá mi, níbi tí mo tí ń retí ìmúṣẹ ìlérí rẹ. Mo ní, “Nígbà wo ni o óo tù mí ninu?” Mo dàbí agbè ọtí tí ó ti di àlòpatì, sibẹ, n kò gbàgbé ìlànà rẹ. Èmi iranṣẹ rẹ yóo ti dúró pẹ́ tó? Nígbà wo ni ìwọ óo dájọ́ fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi? Àwọn onigbeeraga ti gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí, àní, àwọn tí kì í pa òfin rẹ mọ́. Gbogbo òfin rẹ ló dájú; ràn mí lọ́wọ́, nítorí wọ́n ń fi ìwà èké ṣe inúnibíni mi. Wọ́n fẹ́rẹ̀ pa mí run láyé, ṣugbọn n kò kọ ìlànà rẹ sílẹ̀. Dá ẹ̀mí mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, kí n lè máa mú gbogbo àṣẹ rẹ ṣẹ. OLUWA, títí lae ni ọ̀rọ̀ rẹ fìdí múlẹ̀ lọ́run. Òtítọ́ rẹ wà láti ìrandíran; o ti fi ìdí ayé múlẹ̀, ó sì dúró. Ohun gbogbo wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà rẹ, títí di òní, nítorí pé iranṣẹ rẹ ni gbogbo wọn. Bí kò bá jẹ́ pé òfin rẹ jẹ́ ìdùnnú mi, ǹ bá ti ṣègbé ninu ìpọ́njú. Lae, n kò ní gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ, nítorí pé, nípasẹ̀ wọn ni o fi mú mi wà láyé. Ìwọ ni o ni mí, gbà mí; nítorí pé mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ rẹ. Àwọn eniyan burúkú ba dè mí, wọ́n fẹ́ pa mí run, ṣugbọn mò ń ṣe àṣàrò lórí òfin rẹ. Mo ti rí i pé kò sí ohun tí ó lè pé tán, àfi òfin rẹ nìkan ni kò lópin.