Saamu 119:153-176

Saamu 119:153-176 YCB

Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ. Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, OLúWA; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ. Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́. Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ; pa ayé mi mọ́, OLúWA, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni. Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀. Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ. Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo rẹ. Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ, kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀. Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, OLúWA, èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ. Èmi gba òfin rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀ Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi. Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, OLúWA; fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ. Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, OLúWA, àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi. Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró. Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.