O. Daf 119:153-176

O. Daf 119:153-176 Bibeli Mimọ (YBCV)

Wò ipọnju mi, ki o si gbà mi: nitori ti emi kò gbagbe ofin rẹ. Gbà ẹjọ mi rò, ki o rà mi pada: sọ mi di ãye nipa ọ̀rọ rẹ. Igbala jina si awọn enia buburu: nitori ti nwọn kò wá ilana rẹ. Ọ̀pọ ni irọnu ãnu rẹ, Oluwa: sọ mi di ãye gẹgẹ bi idajọ rẹ. Ọ̀pọ li awọn oninunibini mi ati awọn ọta mi; ṣugbọn emi kò fà sẹhin kuro ninu ẹri rẹ. Emi wò awọn ẹlẹtan, inu mi si bajẹ; nitori ti nwọn kò pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Wò bi emi ti fẹ ẹkọ́ rẹ: Oluwa, sọ mi di ãye gẹgẹ bi ãnu rẹ. Otitọ ni ipilẹṣẹ ọ̀rọ rẹ; ati olukulùku idajọ ododo rẹ duro lailai. Awọn ọmọ-alade ṣe inunibini si mi li ainidi: ṣugbọn ọkàn mi warìri nitori ọ̀rọ rẹ. Emi yọ̀ si ọ̀rọ rẹ, bi ẹniti o ri ikogun pupọ. Emi korira, mo si ṣe họ̃ si eke ṣiṣe: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. Nigba meje li õjọ li emi nyìn ọ nitori ododo idajọ rẹ. Alafia pupọ̀ li awọn ti o fẹ ofin rẹ ni: kò si si ohun ikọsẹ fun wọn. Oluwa, emi ti nreti igbala rẹ, emi si ṣe aṣẹ rẹ. Ọkàn mi ti pa ẹri rẹ mọ́; emi si fẹ wọn gidigidi. Emi ti npa ẹkọ́ ati ẹri rẹ mọ́; nitori ti gbogbo ọ̀na mi mbẹ niwaju rẹ. Oluwa, jẹ ki ẹkún mi ki o sunmọ iwaju rẹ: fun mi li oye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Jẹ ki ẹ̀bẹ mi ki o wá siwaju rẹ: gbà mi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Ete mi yio sọ iyìn jade, nigbati iwọ ba ti kọ́ mi ni ilana rẹ. Ahọn mi yio sọ niti ọ̀rọ rẹ: nitori pe ododo ni gbogbo aṣẹ rẹ. Jẹ ki ọwọ rẹ ki o ràn mi lọwọ; nitori ti mo ti yàn ẹkọ rẹ. Oluwa, ọkàn mi ti fà si igbala rẹ; ofin rẹ si ni didùn-inu mi. Jẹ ki ọkàn mi ki o wà lãye, yio si ma yìn ọ; si jẹ ki idajọ rẹ ki o ma ràn mi lọwọ. Emi ti ṣina kiri bi agutan ti o nù; wá iranṣẹ rẹ nitori ti emi kò gbagbe aṣẹ rẹ.

O. Daf 119:153-176 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wo ìpọ́njú mi kí o sì gbà mí, nítorí èmi kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò kí o sì rà mí padà; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn ẹni búburú nítorí wọn kò wá àṣẹ rẹ. Ìyọ́nú rẹ̀ tóbi, OLúWA; pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin rẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ọ̀tá tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi, ṣùgbọ́n èmi kò tí ì yípadà kúrò nínú òfin rẹ. Èmi wo àwọn ẹlẹ́tàn, inú mi sì bàjẹ́ nítorí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ gbọ́. Wo bí èmi ṣe fẹ́ràn ẹ̀kọ́ rẹ; pa ayé mi mọ́, OLúWA, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ; gbogbo òfin òdodo rẹ láéláé ni. Àwọn alákòóso ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí, ṣùgbọ́n ọkàn mi wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ. Èmi yọ̀ nínú ìpinnu rẹ bí ẹni tí ó rí ìkógun púpọ̀. Èmi kórìíra mo sì kọ èké ṣíṣe ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn òfin rẹ. Èmi yìn ọ́ ní ìgbà méje lójúmọ́ nítorí òfin òdodo rẹ. Àlàáfíà púpọ̀ wà fún àwọn tí ó ní ìfẹ́ sí òfin rẹ, kò sì ṣí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀. Èmi yóò dúró de ìgbàlà rẹ, OLúWA, èmi yóò sì tẹ̀lé àṣẹ rẹ. Èmi gba òfin rẹ gbọ́, nítorí mo fẹ́ràn wọn púpọ̀púpọ̀ Èmi ṣe ìgbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ rẹ àti òfin rẹ, nítorí ìwọ mọ gbogbo ọ̀nà mi. Jẹ́ kí igbe mi wá sí iwájú rẹ, OLúWA; fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi wá sí iwájú rẹ; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ. Ètè mi yóò sọ ìyìn jáde, nítorí ìwọ kọ́ mi ní ìlànà rẹ. Jẹ́ kí ahọ́n mi kọ orin ọ̀rọ̀ rẹ, nítorí gbogbo àṣẹ rẹ jẹ́ òdodo. Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣetán láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí èmi ti yan ẹ̀kọ́ rẹ. Èmi wo ọ̀nà fún ìgbàlà rẹ, OLúWA, àti òfin rẹ jẹ́ dídùn inú mi. Jẹ́ kí èmi wà láààyè ki èmi lè yìn ọ́, kí o sì jẹ́ kí òfin rẹ mú mi dúró. Èmí ti ṣìnà bí àgùntàn tí ó sọnù, wá ìránṣẹ́ rẹ, nítorí èmi kò gbàgbé àṣẹ rẹ.

O. Daf 119:153-176 Yoruba Bible (YCE)

Wo ìpọ́njú mi, kí o gbà mí, nítorí n kò gbàgbé òfin rẹ. Gba ẹjọ́ mi rò, kí o sì gbà mí, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ìgbàlà jìnnà sí àwọn eniyan burúkú, nítorí wọn kò wá ìlànà rẹ. Àánú rẹ pọ̀, OLUWA, sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ rẹ. Àwọn tí ń ṣe inúnibíni mi ati àwọn ọ̀tá mi pọ̀, ṣugbọn n kò yapa kúrò ninu ìlànà rẹ. Mò ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀ pẹlu ìríra, nítorí wọn kì í pa òfin rẹ mọ́. Wo bí mo ti fẹ́ ẹ̀kọ́ rẹ tó! Dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀. Òtítọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ, gbogbo òfin òdodo rẹ ni yóo máa wà títí lae. Àwọn ìjòyè ń ṣe inúnibíni mi láìnídìí, ṣugbọn mo bẹ̀rù ọ̀rọ̀ rẹ tọkàntọkàn. Mo láyọ̀ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, bí ẹni pé mo ní ọpọlọpọ ìkógun. Mo kórìíra èké ṣíṣe, ara mi kọ̀ ọ́, ṣugbọn mo fẹ́ràn òfin rẹ. Nígbà meje lojoojumọ ni mò ń yìn ọ́ nítorí òfin òdodo rẹ. Alaafia ńláńlá ń bẹ fún àwọn tí ó fẹ́ràn òfin rẹ, kò sí ohun tí ó lè mú wọn kọsẹ̀. Mò ń retí ìgbàlà rẹ, OLUWA, mo sì ń pa àwọn òfin rẹ mọ́. Mò ń pa àṣẹ rẹ mọ́, mo fẹ́ràn wọn gidigidi. Mo gba ẹ̀kọ́ rẹ, mo sì ń tẹ̀lé ìlànà rẹ; gbogbo ìṣe mi ni ò ń rí. Jẹ́ kí igbe mi dé ọ̀dọ̀ rẹ, OLUWA, fún mi ní òye gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ mi dé iwájú rẹ, kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ. Ẹnu mi yóo kún fún ìyìn rẹ, pé o ti kọ́ mi ní ìlànà rẹ. N óo máa fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe orin kọ, nítorí pé gbogbo òfin rẹ ni ó tọ̀nà. Múra láti ràn mí lọ́wọ́, nítorí pé mo ti gba ẹ̀kọ́ rẹ. Ọkàn mi ń fà sí ìgbàlà rẹ, OLUWA; òfin rẹ sì ni inú dídùn mi. Dá mi sí kí n lè máa yìn ọ́, sì jẹ́ kí òfin rẹ ràn mí lọ́wọ́. Mo ti ṣìnà bí aguntan tó sọnù; wá èmi, iranṣẹ rẹ, rí, nítorí pé n kò gbàgbé òfin rẹ.