Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ọ̀nà wọn wà láìlẹ́ṣẹ̀,
ẹni tí í rìn ní ìbámu pẹ̀lú òfin OLúWA,
Ìbùkún ni fún àwọn ẹni tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́
tí wọn sì ń wá a pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn.
Wọn kò ṣe ohun tí kò dára;
wọ́n rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀
kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.
Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin
láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!
Nígbà náà, ojú kò ní tì mí
nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.
Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin
bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.
Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀:
Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.
Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.
Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi
má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.
Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi
kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ
Ìyìn ni fún OLúWA;
kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò
gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.
Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ,
bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.
Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ
èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ
Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ;
èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.
Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;
èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
La ojú mi kí èmi lè ríran rí
ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;
Má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà
nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún
tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,
nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n
ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,
ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
Òfin rẹ ni dídùn inú mi;
àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.
Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
Èmi yára di òfin rẹ mú. OLúWA
má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.
Kọ́ mi, OLúWA, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí òfin rẹ dára.
Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, OLúWA,
ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ;
Nígbà náà ni èmi yóò dá
ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ
Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
láé àti láéláé.
Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
ojú kì yóò sì tì mí,
Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.
Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:
ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,
ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, OLúWA,
èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,
tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi
níbikíbi tí èmi ń gbé.
Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, OLúWA,
èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
nítorí tí mo
gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.