Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ìgbé ayé wọn kò lábàwọ́n,
àní àwọn tí ń rìn gẹ́gẹ́ bí òfin OLUWA.
Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń pa òfin rẹ̀ mọ́,
tí wọn ń fi tọkàntọkàn ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
Àwọn tí wọn kò dẹ́ṣẹ̀,
ṣugbọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
O ti pàṣẹ pé kí á fi tọkàntọkàn pa òfin rẹ mọ́,
Ìbá ti dára tó
tí mo bá lè dúró ṣinṣin ninu ìlànà rẹ!
Òun ni ojú kò fi ní tì mí,
nítorí pé òfin rẹ ni mò ń tẹ̀lé.
N óo yìn ọ́ pẹlu inú mímọ́,
bí mo ṣe ń kọ́ ìlànà òdodo rẹ.
N óo máa pa òfin rẹ mọ́,
má kọ̀ mí sílẹ̀ patapata.
Báwo ni ọdọmọkunrin ṣe lè mú kí ọ̀nà rẹ̀ mọ́?
Nípa títẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ ni.
Tọkàntọkàn ni mo fi ń ṣe ìfẹ́ rẹ,
má jẹ́ kí n ṣìnà kúrò ninu òfin rẹ.
Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn,
kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.
Ìyìn ni fún ọ, OLUWA,
kọ́ mi ní ìlànà rẹ!
Mo fi ẹnu mi kéde gbogbo àṣẹ tí o pa.
Mo láyọ̀ ninu pípa òfin rẹ mọ́,
bí ẹni tí ó ní ọpọlọpọ ọrọ̀.
N óo máa ṣe àṣàrò ninu òfin rẹ,
n óo sì kọjú sí ọ̀nà rẹ.
N óo láyọ̀ ninu àwọn ìlànà rẹ,
n kò ní gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.
Ṣe ọpọlọpọ oore fún èmi iranṣẹ rẹ,
kí n lè wà láàyè,
kí n sì máa tẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
Là mí lójú, kí n lè rí àwọn nǹkan ìyanu
tí ó wà ninu òfin rẹ.
Àlejò ni mí láyé,
má fi òfin rẹ pamọ́ fún mi.
Òùngbẹ títẹ̀lé òfin rẹ ń gbẹ ọkàn mi, nígbà gbogbo.
O bá àwọn onigbeeraga wí, àwọn ẹni ègún,
tí wọn kò pa òfin rẹ mọ́.
Mú ẹ̀gàn ati àbùkù wọn kúrò lára mi,
nítorí pé mo ti pa òfin rẹ mọ́.
Bí àwọn ìjòyè tilẹ̀ gbìmọ̀ràn ọ̀tẹ̀ nítorí mi,
sibẹ, èmi iranṣẹ rẹ yóo ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.
Àwọn òfin rẹ ni dídùn inú mi,
àwọn ni olùdámọ̀ràn mi.
Mo di ẹni ilẹ̀,
sọ mí di alààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
Nígbà tí mo jẹ́wọ́ gbogbo ìṣe mi, o dá mi lóhùn;
kọ́ mi ní ìlànà rẹ.
La òfin rẹ yé mi,
n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí iṣẹ́ ìyanu rẹ.
Ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọkàn mi nítorí ìbànújẹ́,
mú mi lọ́kàn le gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
Mú ìwà èké jìnnà sí mi,
kí o sì fi oore ọ̀fẹ́ kọ́ mi ní òfin rẹ.
Mo ti yan ọ̀nà òtítọ́,
mo ti fi ọkàn sí òfin rẹ.
Mo pa òfin rẹ mọ́, OLUWA,
má jẹ́ kí ojú ó tì mí.
N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́,
nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i.
OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ,
n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin.
Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,
kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́.
Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ,
nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀.
Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ,
kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé.
Yí ojú mi kúrò ninu wíwo nǹkan asán,
sọ mí di alààyè ní ọ̀nà rẹ.
Mú ìlérí rẹ ṣẹ fún iranṣẹ rẹ,
àní, ìlérí tí o ṣe fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ.
Mú ẹ̀gàn tí ń bà mí lẹ́rù kúrò,
nítorí pé ìlànà rẹ dára.
Wò ó, ọkàn mi fà sí ati máa tẹ̀lé ìlànà rẹ,
sọ mí di alààyè nítorí òdodo rẹ!
Fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn mí, OLÚWA,
kí o sì gbà mí là gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ.
Nígbà náà ni n óo lè dá àwọn tí ń gàn mí lóhùn,
nítorí mo gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá,
nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ.
N óo máa pa òfin rẹ mọ́ nígbà gbogbo, lae ati laelae.
N óo máa rìn fàlàlà,
nítorí pé mo tẹ̀lé ìlànà rẹ.
N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba,
ojú kò sì ní tì mí.
Mo láyọ̀ ninu òfin rẹ,
nítorí tí mo fẹ́ràn rẹ̀.
Mo bọ̀wọ̀ fún àṣẹ rẹ tí mo fẹ́ràn,
n óo sì máa ṣe àṣàrò lórí ìlànà rẹ.
Ranti ọ̀rọ̀ tí o bá èmi iranṣẹ rẹ sọ,
èyí tí ó fún mi ní ìrètí.
Ohun tí ó ń tù mí ninu ní àkókò ìpọ́njú ni pé:
ìlérí rẹ mú mi wà láàyè.
Àwọn onigbeeraga ń kẹ́gàn mi gidigidi,
ṣugbọn n ò kọ òfin rẹ sílẹ̀.
Mo ranti òfin rẹ àtijọ́,
OLUWA, ọkàn mi sì balẹ̀.
Inú mi á máa ru,
nígbà tí mo bá rí àwọn eniyan burúkú,
tí wọn ń rú òfin rẹ.
Òfin rẹ ni mò ń fi ń ṣe orin kọ,
lákòókò ìrìn àjò mi láyé.
Mo ranti orúkọ rẹ lóru;
OLUWA, mo sì pa òfin rẹ mọ́:
Èyí ni ìṣe mi:
Èmi a máa pa òfin rẹ mọ́.