Ẹ máa yin OLúWA. Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ OLúWA, ẹ yin orúkọ OLúWA. Fi ìbùkún fún orúkọ OLúWA láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀ orúkọ OLúWA ni kí a máa yìn. OLúWA ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run. Ta ló dàbí OLúWA Ọlọ́run wa, tí ó gbé ní ibi gíga. Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé! Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá. Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé, àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.
Kà Saamu 113
Feti si Saamu 113
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Saamu 113:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò