Ẹ ma yìn Oluwa! Ẹ ma yìn, ẹnyin iranṣẹ Oluwa, ẹ ma yìn orukọ Oluwa. Ibukún li orukọ Oluwa lati isisiyi lọ ati si i lailai. Lati ila-õrun titi o fi de ìwọ rẹ̀ orukọ Oluwa ni ki a yìn. Oluwa ga lori gbogbo orilẹ-ède, ogo rẹ̀ si wà lori ọrun. Tali o dabi Oluwa Ọlọrun wa, ti o ngbe ibi giga. Ẹniti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ lati wò ohun ti o wà li ọrun ati li aiye! O gbé talaka soke lati inu erupẹ wá, o si gbé olupọnju soke lati ori àtan wá; Ki o le mu u joko pẹlu awọn ọmọ-alade, ani pẹlu awọn ọmọ-alade awọn enia rẹ̀. O mu àgan obinrin gbe inu ile, lati ma ṣe oninu-didùn iya awọn ọmọ. Ẹ ma yìn Oluwa!
Kà O. Daf 113
Feti si O. Daf 113
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Daf 113:1-9
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò