Saamu 103:1-13

Saamu 103:1-13 YCB

Yin OLúWA, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́. Yin OLúWA, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀ Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́ tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn, Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé, Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì. OLúWA ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún gbogbo àwọn tí a ni lára. Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli; OLúWA ni aláàánú àti olóore, ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́. Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé; Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́ bí àìṣedéédéé wa. Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀. Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa. Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLúWA ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀