O. Daf 103:1-13

O. Daf 103:1-13 YBCV

FI ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, ati gbogbo ohun ti o wà ninu mi, fi ibukún fun orukọ rẹ̀ mimọ́. Fi ibukún fun Oluwa, iwọ ọkàn mi, má si ṣe gbagbe gbogbo ore rẹ̀: Ẹniti o dari gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ jì; ẹniti o si tan gbogbo àrun rẹ, Ẹniti o ra ẹmi rẹ kuro ninu iparun; ẹniti o fi iṣeun-ifẹ ati iyọ́nu de ọ li ade: Ẹniti o fi ohun didara tẹ́ ọ lọrun: bẹ̃ni igba ewe rẹ di ọtun bi ti idì. Oluwa ṣe ododo ati idajọ fun gbogbo awọn ti a nilara. O fi ọ̀na rẹ̀ hàn fun Mose, iṣe rẹ̀ fun awọn ọmọ Israeli. Oluwa li alãnu ati olõre, o lọra ati binu, o si pọ̀ li ãnu. On kì ibaniwi nigbagbogbo: bẹ̃ni kì ipa ibinu rẹ̀ mọ́ lailai. On kì iṣe si wa gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ wa; bẹ̃ni kì isan a fun wa gẹgẹ bi aiṣedede wa. Nitori pe, bi ọrun ti ga si ilẹ, bẹ̃li ãnu rẹ̀ tobi si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀. Bi ila-õrun ti jina si ìwọ-õrun, bẹ̃li o mu irekọja wa jina kuro lọdọ wa. Bi baba ti iṣe iyọ́nu si awọn ọmọ, bẹ̃li Oluwa nṣe iyọ́nu si awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀.