Òwe 23:1-18

Òwe 23:1-18 YCB

Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi. Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun, bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn. Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀: nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni. Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀: ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ. Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí? Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀, ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run. Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀. Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí: “Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ; ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ. Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde, ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù. Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè; nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ. Má ṣe ṣí ààlà àtijọ́ kúrò; má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba. Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára; yóò gba ìjà wọn jà sí ọ. Fi àyà sí ẹ̀kọ́, àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀-ìmọ̀. Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé, nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú. Bí ìwọ fi pàṣán nà án, ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run àpáàdì. Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n, ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú. Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù OLúWA, ní ọjọ́ gbogbo. Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́; ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.