Owe 23:1-18
Owe 23:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBATI iwọ ba joko lati ba ijoye jẹun, kiyesi ẹniti o wà niwaju rẹ gidigidi. Ki o si fi ọbẹ le ara rẹ li ọfun, bi iwọ ba iṣe okundùn enia. Máṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀: nitoripe onjẹ ẹ̀tan ni. Máṣe lãla ati lọrọ̀: ṣiwọ kuro ninu imoye ara rẹ. Iwọ o ha fi oju rẹ wò o? kì yio si si mọ, nitoriti ọrọ̀ hu iyẹ-apá fun ara rẹ̀ bi ìdi ti nfò li oju ọrun. Máṣe jẹ onjẹ oloju buburu, bẹ̃ni ki o má si ṣe fẹ onjẹ-didùn rẹ̀. Nitoripe bi o ti nṣiro li ọkàn rẹ̀, bẹ̃ li o ri: mã jẹ, ki o si ma mu li o nwi fun ọ; ṣugbọn ọkàn rẹ̀ kò pẹlu rẹ. Okele ti iwọ jẹ ni iwọ o pọ̀ jade, iwọ a si sọ ọ̀rọ didùn rẹ nù. Máṣe sọ̀rọ li eti aṣiwère: nitoriti yio gàn ọgbọ́n ọ̀rọ rẹ. Máṣe ṣi àla atijọ; má si ṣe bọ sinu oko alaini-baba. Nitoripe Olurapada wọn lagbara; yio gbà ìja wọn ja ti awọn tirẹ. Fi aiya si ẹkọ́, ati eti rẹ si ọ̀rọ ìmọ. Máṣe fà ọwọ ibawi sẹhin kuro lara ọmọde, nitoripe bi iwọ ba fi paṣan nà a, on kì yio kú. Iwọ fi paṣan nà a, iwọ o si gbà ọkàn rẹ̀ la kuro li ọrun-apadi. Ọmọ mi, bi ọkàn rẹ ba gbọ́n ọkàn mi yio yọ̀, ani emi pẹlu. Inu mi yio si dùn nigbati ètè rẹ ba nsọ̀rọ titọ. Máṣe jẹ ki aiya rẹ ki o ṣe ilara si awọn ẹ̀lẹṣẹ, ṣugbọn ki iwọ ki o wà ni ibẹ̀ru Oluwa, li ọjọ gbogbo. Nitoripe ikẹhin mbẹ nitõtọ; ireti rẹ kì yio si ke kuro.

Owe 23:1-18 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí o bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsí ẹni tí ó bá wà níwájú rẹ dáradára. Tí o bá jẹ́ wọ̀bìà eniyan, ṣọ́ra, kí o má fi ọ̀bẹ lé ara rẹ lọ́fun. Má jẹ́ kí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú, nítorí ó lè jẹ́ oúnjẹ ẹ̀tàn. Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ, fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ. Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ, ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò, bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ. Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun, má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀; nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni. Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!” ṣugbọn kò dé inú rẹ̀. O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ, gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù. Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀, nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ. Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́, má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba; nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára, yóo gba ìjà wọn jà. Fi ọkàn rẹ sí ẹ̀kọ́, kí o sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀. Bá ọmọde wí; bí o bá fi pàṣán nà án, kò ní kú. Bí o bá fi pàṣán nà án, o óo gba ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Ọmọ mi, bí o bá gbọ́n, inú mi yóo dùn. N óo láyọ̀ ninu ọkàn mi nígbà tí o bá ń sọ òtítọ́. Má ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn máa bẹ̀rù OLUWA lọ́jọ́ gbogbo. Dájúdájú, ọjọ́ ọ̀la rẹ yóo dára, ìrètí rẹ náà kò sì ní já sí òfo.
Owe 23:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi. Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun, bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn. Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀: nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni. Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀: ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ. Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí? Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀, ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run. Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀. Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí: “Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ; ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ. Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde, ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù. Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè; nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ. Má ṣe ṣí ààlà àtijọ́ kúrò; má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba. Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára; yóò gba ìjà wọn jà sí ọ. Fi àyà sí ẹ̀kọ́, àti etí rẹ sí ọ̀rọ̀-ìmọ̀. Má ṣe fa ọwọ́ ìbáwí sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé, nítorí pé bí ìwọ bá fi pàṣán nà án, òun kì yóò kú. Bí ìwọ fi pàṣán nà án, ìwọ ó sì gbà ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run àpáàdì. Ọmọ mi, bí ọkàn rẹ bá gbọ́n, ọkàn mi yóò yọ̀, àní èmi pẹ̀lú. Inú mi yóò sì dùn nígbà tí ètè rẹ̀ bá ń sọ̀rọ̀ títọ́. Má ṣe jẹ́ kí àyà rẹ ó ṣe ìlara sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó wà ní ìbẹ̀rù OLúWA, ní ọjọ́ gbogbo. Nítorí pé ìgbẹ̀yìn ń bẹ nítòótọ́; ìrètí rẹ̀ kì yóò sì gé kúrò.