ÌWÉ ÒWE 23:1-18

ÌWÉ ÒWE 23:1-18 YCE

Nígbà tí o bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun, kíyèsí ẹni tí ó bá wà níwájú rẹ dáradára. Tí o bá jẹ́ wọ̀bìà eniyan, ṣọ́ra, kí o má fi ọ̀bẹ lé ara rẹ lọ́fun. Má jẹ́ kí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀ wọ̀ ọ́ lójú, nítorí ó lè jẹ́ oúnjẹ ẹ̀tàn. Má ṣe làálàá àṣejù láti kó ọrọ̀ jọ, fi ọgbọ́n sẹ́ ara rẹ. Kí o tó ṣẹ́jú pẹ́, owó rẹ lè ti lọ, ó le gúnyẹ̀ẹ́ kí ó fò, bí ìgbà tí ẹyẹ àṣá bá fò lọ. Má ṣe jẹ oúnjẹ ahun, má ní ìfẹ́ sí oúnjẹ aládìídùn rẹ̀; nítorí ẹni tí ó máa fi ọkàn ṣírò owó oúnjẹ ni. Ó lè máa wí fún ọ pé, “Jẹ, kí o sì mu!” ṣugbọn kò dé inú rẹ̀. O óo pọ gbogbo òkèlè tí o jẹ, gbogbo ọ̀rọ̀ dídùn tí o sọ yóo sì jẹ́ àsọdànù. Má sọ̀rọ̀ létí òmùgọ̀, nítorí yóo gan ọgbọ́n tí ó wà ninu ọ̀rọ̀ tí o sọ. Má ṣe hú ohun tí wọ́n rì mọ́lẹ̀ fi pa ààlà láti ìgbà àtijọ́, má sì gba ilẹ̀ ọmọ aláìníbaba; nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára, yóo gba ìjà wọn jà. Fi ọkàn rẹ sí ẹ̀kọ́, kí o sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ ìmọ̀. Bá ọmọde wí; bí o bá fi pàṣán nà án, kò ní kú. Bí o bá fi pàṣán nà án, o óo gba ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Ọmọ mi, bí o bá gbọ́n, inú mi yóo dùn. N óo láyọ̀ ninu ọkàn mi nígbà tí o bá ń sọ òtítọ́. Má ṣe ìlara àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn máa bẹ̀rù OLUWA lọ́jọ́ gbogbo. Dájúdájú, ọjọ́ ọ̀la rẹ yóo dára, ìrètí rẹ náà kò sì ní já sí òfo.