Òwe 20:16-30

Òwe 20:16-30 YCB

Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò; mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn. Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀. Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà. Olófòófó a máa tú àṣírí nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀. Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri. Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín. Má ṣe wí pé, “N ó ṣẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ” Dúró de OLúWA yóò sì gbà ọ́ là. OLúWA kórìíra òdínwọ̀n èké. Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn. OLúWA ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni? Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò. Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká; Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n. Àtùpà OLúWA ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú. Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́, nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu. Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn, ewú orí ni iyì arúgbó. Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ, pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa