Owe 20:16-30
Owe 20:16-30 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gba aṣọ rẹ̀, nitori ti o ṣe onigbọwọ fun alejo, si gba ohun ẹrí lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin. Onjẹ ẹ̀tan dùn mọ enia; ṣugbọn nikẹhin, ẹnu rẹ̀ li a o fi tarã kún. Igbimọ li a fi ifi idi ete gbogbo kalẹ: ati pẹlu èro rere ni ki o ṣigun. Ẹniti o ba nkiri bi olofofo a ma fi ọ̀ran ìkọkọ hàn: má si ṣe ba ẹniti nṣi ète rẹ̀ ṣire. Ẹnikẹni ti o ba bú baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀, fitila rẹ̀ li a o pa ninu òkunkun biribiri. Ogún ti a yara jẹ latetekọṣe, li a kì yio bukún li opin rẹ̀. Iwọ máṣe wipe, Emi o gbẹsan ibi; ṣugbọn duro de Oluwa, on o si gbà ọ. Ìwọn miran, ati òṣuwọn miran, irira ni loju Oluwa; ìwọn irẹjẹ kò si dara. Irin ti enia nrìn, lati ọdọ Oluwa ni; tani ninu awọn enia ti o le mọ̀ ọ̀na rẹ̀? Idẹkùn ni fun enia lati yara ṣe ileri mimọ́, ati lẹhin ẹjẹ́, ki o ma ronu. Ọlọgbọ́n ọba a tú enia buburu ka, a si mu ayika-kẹkẹ́ rẹ̀ kọja lori wọn. Ẹmi enia ni fitila Oluwa, a ma ṣe awari iyara inu. Anu ati otitọ pa ọba mọ́: ãnu li a si fi ndi itẹ́ rẹ̀ mu. Ogo awọn ọdọmọkunrin li agbara wọn: ẹwà awọn arugbo li ewú. Apá ọgbẹ ni iwẹ̀ ibi nù kuro: bẹ̃ si ni ìna ti o wọ̀ odò ikùn lọ.
Owe 20:16-30 Yoruba Bible (YCE)
Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò, gba aṣọ ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ ẹni tí kò mọ̀ rí. Oúnjẹ tí a bá rí lọ́nà èrú máa ń dùn lẹ́nu eniyan, ṣugbọn nígbà tí a bá jẹ ẹ́ tán, ẹnu ẹni a máa kan. Ìmọ̀ràn níí fìdí ètò múlẹ̀, gba ìtọ́sọ́nà kí o tó lọ jagun. Ẹni tí ó ń ṣe òfófó káàkiri a máa tú ọpọlọpọ àṣírí, nítorí náà má ṣe bá ẹlẹ́jọ́ kẹ́gbẹ́. Bí eniyan bá ń fi baba tabi ìyá rẹ̀ bú, àtùpà rẹ̀ yóo kú láàrin òkùnkùn biribiri. Ogún tí a fi ìkánjú kójọ níbẹ̀rẹ̀, kì í ní ibukun nígbẹ̀yìn. Má sọ pé o fẹ́ fi burúkú san burúkú, gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, yóo sì gbà ọ́. Ayédèrú òṣùnwọ̀n jẹ́ ohun ìríra lójú OLUWA, ìwọ̀n èké kò dára. OLUWA ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni, eniyan kò lè ní òye ọ̀nà ara rẹ̀. Ronú jinlẹ̀ kí o tó jẹ́jẹ̀ẹ́ fún OLUWA, kí o má baà kábàámọ̀ rẹ̀. Ọba tó gbọ́n a máa fẹ́ eniyan burúkú dànù, a sì lọ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ̀mí eniyan ni fìtílà OLUWA, tíí máa wá gbogbo kọ́lọ́fín inú rẹ̀ kiri. Ìfẹ́ ati òtítọ́ níí mú kí ọba pẹ́, òdodo níí sì ń gbé ìjọba rẹ̀ ró. Agbára ni ògo ọ̀dọ́, ewú sì ni ẹwà àgbà. Ìjìyà tó fa ọgbẹ́ a máa mú ibi kúrò, pàṣán a máa mú kí inú mọ́.
Owe 20:16-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gba abọ́ ẹni tí ó ṣe onídùúró fún àlejò; mú un lọ́wọ́ bí ìbúra bí ó bá ṣe é fún obìnrin onírìnkurìn. Oúnjẹ tí a fi ọ̀nà èrú rí máa ń dùn lẹ́nu ènìyàn ṣùgbọ́n, a yọrí sí ibi ẹnu tí ó kún fún erùpẹ̀. Pa ètè rẹ mọ́ nípa wíwá ìmọ̀ràn bí o bá ń jagun, gba ìtọ́sọ́nà. Olófòófó a máa tú àṣírí nítorí náà yẹra fún ènìyàn tí ń rojọ́ púpọ̀. Bí ènìyàn kan bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ni a ó pa kú nínú òkùnkùn biribiri. Ogún tí a kójọ kíákíá ní ìbẹ̀rẹ̀ kì yóò ní ìbùkún ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín. Má ṣe wí pé, “N ó ṣẹ̀san àṣìṣe rẹ yìí fún ọ” Dúró de OLúWA yóò sì gbà ọ́ là. OLúWA kórìíra òdínwọ̀n èké. Òṣùwọ̀n ìrẹ́jẹ kò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn. OLúWA ni ó ń ṣe olùdarí ìgbésẹ̀ ènìyàn Báwo wá ni òye gbogbo ọ̀nà ènìyàn ṣe le yé ni? Ìdẹ̀kùn ni fún ènìyàn láti ṣe ìlérí kíákíá nígbà tí ó bá sì yá kí ó máa ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wò. Ọlọ́gbọ́n ọba tú ènìyàn búburú ká; Ó sì fi òòlọ ìpakà lọ̀ wọ́n. Àtùpà OLúWA ń ṣe àwárí ẹ̀mí ènìyàn a máa ṣàwárí ibi ìkọ̀kọ̀ inú. Ìfẹ́ àti òdodo pa ọba mọ́, nípa ìfẹ́, ìtẹ́ rẹ̀ wà láìléwu. Ògo àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ni agbára wọn, ewú orí ni iyì arúgbó. Ìgbájú ìgbámú àti ìfarapa máa ń mú ibi lọ, pàṣán sì máa ń ṣe àfọ̀mọ́ ibi ìkọ̀kọ̀ inú.