Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà. Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀ tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà. Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnrarẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí OLúWA. Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́. Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí; gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́. Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un! Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, kò tilẹ̀ le rí wọn rárá. Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀; ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú. Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun. Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá, mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé. Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù; fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá. Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún, ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko. Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò. A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ OLúWA ni.
Kà Òwe 19
Feti si Òwe 19
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Òwe 19:1-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò