Owe 19:1-14

Owe 19:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Talaka tí ń rìn pẹlu òtítọ́ inú, ó sàn ju òmùgọ̀ eniyan, tí ó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn lọ. Kò dára kí eniyan wà láìní ìmọ̀, ẹni bá ń kánjú rìn jù a máa ṣìnà. Nígbà tí ìwà òmùgọ̀ bá kó ìparun bá a, ọkàn rẹ̀ a máa bá OLUWA bínú. Ọrọ̀ a máa mú kí eniyan ní ọpọlọpọ ọ̀rẹ́ titun, ṣugbọn àwọn ọ̀rẹ́ talaka a máa kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, bẹ́ẹ̀ ni òpùrọ́ kò ní bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀san ibi. Ọ̀pọ̀ eniyan níí máa ń wá ojurere ẹni tó lawọ́, gbogbo eniyan sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ń fúnni lẹ́bùn. Gbogbo àwọn arakunrin talaka ni wọ́n kórìíra rẹ̀, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jìnnà sí i! Ó fọ̀rọ̀ ẹnu fà wọ́n títí, sibẹ wọn kò súnmọ́ ọn. Ẹni tí ó ní ọgbọ́n fẹ́ràn ara rẹ̀, ẹni tí ó bá sì ní òye, yóo ṣe rere. Ẹlẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó ń pa irọ́ yóo parun. Ìgbádùn kò yẹ òmùgọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ kí ẹrú jọba lórí àwọn ìjòyè. Ọgbọ́n kì í jẹ́ kí ọlọ́gbọ́n yára bínú, ògo rẹ̀ sì níláti fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ dá. Ibinu ọba dàbí bíbú kinniun, ṣugbọn ojurere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko tútù. Òmùgọ̀ ọmọ lè kó ìparun bá baba rẹ̀, iyawo oníjà dàbí omi òjò tí ń kán tó, tó, tó, láì dáwọ́ dúró. A máa ń jogún ilé ati ọrọ̀ lọ́wọ́ baba ẹni, ṣugbọn OLUWA níí fúnni ní aya rere.

Owe 19:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà. Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀ tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà. Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnrarẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run; síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí OLúWA. Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́. Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí; gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́. Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un! Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀, kò tilẹ̀ le rí wọn rárá. Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀; ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú. Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun. Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá, mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé. Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù; fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá. Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún, ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko. Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀, Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò. A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ OLúWA ni.