Owe 19:1-14

Owe 19:1-14 YBCV

TALAKA ti nrìn ninu ìwa-titọ rẹ̀, o san jù ẹniti o nṣe arekereke li ète rẹ̀ lọ, ti o si nṣe wère. Pẹlupẹlu, ọkàn laini ìmọ, kò dara; ẹniti o ba si fi ẹsẹ rẹ̀ yara yio ṣubu. Wère enia yi ọ̀na rẹ̀ po: nigbana ni aiya rẹ̀ binu si Oluwa. Ọrọ̀ fà ọrẹ́ pupọ; ṣugbọn talaka di yiyà kuro lọdọ aladugbo rẹ̀. Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ati ẹniti o si nṣeke kì yio mu u jẹ. Ọpọlọpọ ni yio ma bẹ̀bẹ ojurere ọmọ-alade: olukuluku enia ni si iṣe ọrẹ́ ẹniti ntani li ọrẹ. Gbogbo awọn arakunrin talaka ni ikorira rẹ̀: melomelo ni awọn ọrẹ́ rẹ̀ yio ha jina si i? o ntẹle ọ̀rọ wọn, ṣugbọn nwọn kò si. Ẹniti o gbọ́n, o fẹ ọkàn ara rẹ̀: ẹniti o pa oye mọ́ yio ri rere. Ẹlẹri eke kì yio lọ laijiya, ẹniti o si nṣeke yio ṣegbe. Ohun rere kò yẹ fun aṣiwère; tabi melomelo fun iranṣẹ lati ṣe olori awọn ijoye. Imoye enia mu u lọra ati binu; ogo rẹ̀ si ni lati ré ẹ̀ṣẹ kọja. Ibinu ọba dabi igbe kiniun; ṣugbọn ọjurere rẹ̀ dabi ìri lara koriko. Aṣiwère ọmọ ni ibanujẹ baba rẹ̀: ìja aya dabi ọ̀ṣọrọ òjo. Ile ati ọrọ̀ li ogún awọn baba: ṣugbọn amoye aya, lati ọdọ Oluwa wá ni.