Òwe 11:1-15

Òwe 11:1-15 YCB

OLúWA kórìíra òṣùwọ̀n èké, ṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀. Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá. Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀. Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́. Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo. A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú. Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà. Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan. Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run. Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́. Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́. Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú. Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu.