Owe 11:1-15
Owe 11:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
OṢUWỌN eke irira ni loju Oluwa; ṣugbọn òṣuwọn otitọ ni didùn inu rẹ̀. Bi igberaga ba de, nigbana ni itiju de, ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu onirẹlẹ. Otitọ aduro-ṣinṣin ni yio ma tọ́ wọn; ṣugbọn arekereke awọn olurekọja ni yio pa wọn run. Ọrọ̀ kì ini anfani li ọjọ ibinu: ṣugbọn ododo ni igbani lọwọ ikú. Ododo ẹni-pipé yio ma tọ́ ọ̀na rẹ̀: ṣugbọn enia buburu yio ṣubu ninu ìwa-buburu rẹ̀. Ododo awọn aduro-ṣinṣin yio gbà wọn là: ṣugbọn awọn olurekọja li a o mu ninu iṣekuṣe wọn: Nigbati enia buburu ba kú, ireti rẹ̀ a dasan, ireti awọn alaiṣedede enia a si dasan. A yọ olododo kuro ninu iyọnu, enia buburu a si bọ si ipò rẹ̀. Ẹnu li agabagebe ifi pa aladugbo rẹ̀: ṣugbọn ìmọ li a o fi gbà awọn olododo silẹ. Nigbati o ba nṣe rere fun olododo, ilu a yọ̀: nigbati enia buburu ba ṣegbe, igbe-ayọ̀ a ta. Nipa ibukún aduro-ṣinṣin ilu a gbé lèke: ṣugbọn a bì i ṣubu nipa ẹnu enia buburu. Ẹniti oye kù fun gàn ọmọnikeji rẹ̀; ṣugbọn ẹni oye a pa ẹnu rẹ̀ mọ́. Ẹniti nṣofofo fi ọ̀ran ipamọ́ hàn; ṣugbọn ẹniti nṣe olõtọ-ọkàn a pa ọ̀rọ na mọ́. Nibiti ìgbimọ kò si, awọn enia a ṣubu; ṣugbọn ninu ọ̀pọlọpọ ìgbimọ ni ailewu. Ẹniti o ba ṣe onigbọwọ fun alejo, ni yio ri iyọnu; ẹniti o ba si korira iṣegbọwọ wà lailewu.
Owe 11:1-15 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA kórìíra òṣùnwọ̀n èké, òṣùnwọ̀n tí ó péye ni inú rẹ̀ dùn sí. Bí ìgbéraga bá wọlé, àbùkù a tẹ̀lé e, ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu àwọn onírẹ̀lẹ̀. Òtítọ́ inú àwọn olódodo a máa tọ́ wọn, ṣugbọn ìwà aiṣootọ àwọn ọ̀dàlẹ̀ níí pa wọ́n. Ọrọ̀ kò jámọ́ nǹkankan ní ọjọ́ ibinu, ṣugbọn òdodo a máa gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, Òdodo ẹni pípé a máa mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ṣugbọn ẹni ibi ṣubú nípa ìwà ìkà rẹ̀. Ìwà òdodo àwọn olóòótọ́ yóo gbà wọ́n, ṣugbọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dàlẹ̀ yóo dè wọ́n nígbèkùn. Nígbà tí àwọn eniyan burúkú bá kú, ìrètí wọn yóo di asán, bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn tí kò mọ Ọlọrun yóo di òfo. OLUWA a máa gba olódodo lọ́wọ́ ìyọnu, ṣugbọn ẹni ibi a bọ́ sinu wahala. Ẹni tí kò mọ Ọlọrun a máa fi ẹnu ba ti aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣugbọn nípa ìmọ̀ a máa gba olódodo sílẹ̀. Nígbà tí nǹkan bá ń dára fún olódodo, gbogbo ará ìlú a máa yọ̀, nígbà tí eniyan burúkú bá kú, gbogbo ará ìlú a sì hó ìhó ayọ̀. Ìre tí olódodo bá sú fún ìlú a máa gbé orúkọ ìlú ga, ṣugbọn ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn eniyan burúkú a máa run ìlú. Ẹni tí ó tẹmbẹlu aládùúgbò rẹ̀ kò gbọ́n, ṣugbọn ọlọ́gbọ́n a máa pa ẹnu mọ́. Olófòófó a máa tú àṣírí, ṣugbọn ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a máa pa àṣírí mọ́. Níbi tí kò bá ti sí ìtọ́ni, orílẹ̀-èdè a máa ṣubú, ṣugbọn ẹni tí ó bá ní ọpọlọpọ olùdámọ̀ràn yóo máa gbé ní àìléwu. Ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò yóo rí ìyọnu, ṣugbọn ẹni tí ó bá kọ̀ tí kò ṣe onídùúró yóo wà láìléwu.

Owe 11:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA kórìíra òṣùwọ̀n èké, ṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀. Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá. Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú. Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fà á lulẹ̀. Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là ṣùgbọ́n ìdẹ̀kùn ètè búburú mú aláìṣòótọ́. Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun gbogbo ohun tó ń fojú ṣọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já ṣófo. A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú. Aláìmọ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ olódodo sá àsálà. Nígbà tí olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan. Nípasẹ̀ ìbùkún, olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run. Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́. Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́. Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú. Ẹni tí ó ṣe onígbọ̀wọ́ fún àlejò yóò rí ìyọnu, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onígbọ̀wọ́ yóò wà láìléwu.