Numeri 16:41-50

Numeri 16:41-50 YCB

Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kùn sí Mose àti Aaroni pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn OLúWA.” Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mose àti Aaroni, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkùùkuu bolẹ̀, ògo OLúWA sì fi ara hàn. Nígbà náà ni Mose àti Aaroni lọ síwájú àgọ́ ìpàdé, OLúWA sì sọ fún Mose pé, “Yàgò kúrò láàrín ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan.” Wọ́n sì dojúbolẹ̀. Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárín ìjọ ènìyàn láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú OLúWA ti jáde, àjàkálẹ̀-ààrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.” Aaroni ṣe bí Mose ti wí, ó sáré lọ sí àárín àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrín wọn, ṣùgbọ́n Aaroni fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn. Ó dúró láàrín àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dúró. Ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti pa ẹgbàá-méje ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (14,700) ènìyàn ní àfikún sí àwọn tí ó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Kora. Aaroni padà tọ Mose lọ ní ẹnu-ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé nítorí pé àjàkálẹ̀-ààrùn náà ti dúró.