Num 16:41-50
Num 16:41-50 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ keji gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Mose ati Aaroni pé, “Ẹ pa àwọn eniyan OLUWA.” Ó sì ṣe nígbà tí àwọn eniyan náà kó ara wọn jọ láti dojú kọ Mose ati Aaroni, wọn bojúwo ìhà Àgọ́ Àjọ, wọ́n sì rí i tí ìkùukùu bò ó, ògo OLUWA sì farahàn. Mose ati Aaroni lọ dúró níwájú Àgọ́ Àjọ, OLUWA sì sọ fún Mose pé, “Kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi kí n lè pa wọ́n run ní ìṣẹ́jú kan.” Mose ati Aaroni bá dojúbolẹ̀. Mose sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo turari rẹ, fi ẹ̀yinná sinu rẹ̀ láti orí pẹpẹ kí o sì fi turari sí i. Ṣe kíá, lọ sọ́dọ̀ àwọn eniyan náà láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí ibinu OLUWA ti ru, àjàkálẹ̀ àrùn sì ti bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.” Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Mose. Ó mú àwo turari rẹ̀, ó sáré lọ sí ààrin àwọn eniyan náà. Nígbà tí ó rí i pé àjàkálẹ̀ àrùn ti bẹ́ sílẹ̀, ó fi turari sí i, ó sì ṣe ètùtù fún wọn. Aaroni dúró ní ààrin àwọn òkú ati alààyè, àjàkálẹ̀ àrùn náà sì dáwọ́ dúró. Àwọn tí ó kú jẹ́ ẹgbaa meje ó lé ẹẹdẹgbẹrin (14,700) láìka àwọn tí ó kú pẹlu Kora. Nígbà tí àjàkálẹ̀ àrùn náà dáwọ́ dúró, Aaroni pada sọ́dọ̀ Mose lẹ́nu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.
Num 16:41-50 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ni ijọ́ keji gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli nkùn si Mose ati si Aaroni, wipe, Ẹnyin pa awọn enia OLUWA. O si ṣe, nigbati ijọ pejọ pọ̀ si Mose ati si Aaroni, ti nwọn si wò ìha agọ́ ajọ: si kiyesi i, awọsanma bò o, ogo OLUWA si farahàn. Mose ati Aaroni si wá siwaju agọ́ ajọ. OLUWA si sọ fun Mose pe, Ẹ lọ kuro lãrin ijọ yi, ki emi ki o run wọn ni iṣẹju kan. Nwọn si doju wọn bolẹ. Mose si wi fun Aaroni pe, Mú awo-turari kan, ki o si fi iná sinu rẹ̀ lati ori pẹpẹ nì wá, ki o si fi turari lé ori rẹ̀, ki o si yára lọ sọdọ ijọ, ki o si ṣètutu fun wọn: nitoriti ibinu jade lati ọdọ OLUWA lọ; iyọnu ti bẹ̀rẹ na. Aaroni si mú awo-turari bi Mose ti fi aṣẹ fun u, o si sure lọ sãrin ijọ; si kiyesi i, iyọnu ti bẹ̀rẹ na lãrin awọn enia: o si fi turari sinu rẹ̀, o si ṣètutu fun awọn enia na. O si duro li agbedemeji okú ati alãye; iyọnu na si duro. Awọn ti o kú ninu iyọnu na si jẹ́ ẹgba meje o le ẹ̃dẹgbẹrin, laìka awọn ti o kú niti ọ̀ran Kora. Aaroni si pada tọ̀ Mose lọ si ibi ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: iyọnu na si duro.
Num 16:41-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ kejì gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli kùn sí Mose àti Aaroni pé, “Ẹ ti pa àwọn ènìyàn OLúWA.” Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn péjọ lòdì sí Mose àti Aaroni, níwájú àgọ́ ìpàdé, lójijì ni ìkùùkuu bolẹ̀, ògo OLúWA sì fi ara hàn. Nígbà náà ni Mose àti Aaroni lọ síwájú àgọ́ ìpàdé, OLúWA sì sọ fún Mose pé, “Yàgò kúrò láàrín ìjọ ènìyàn yìí, kí ń ba le run wọ́n ní ìṣẹ́jú kan.” Wọ́n sì dojúbolẹ̀. Mose sì sọ fún Aaroni pé, “Mú àwo tùràrí, kí o fi iná sí i lórí pẹpẹ, fi tùràrí sínú rẹ̀, kí o sì tètè mu lọ sí àárín ìjọ ènìyàn láti ṣe ètùtù fún wọn nítorí pé ìbínú OLúWA ti jáde, àjàkálẹ̀-ààrùn sì ti bẹ̀rẹ̀.” Aaroni ṣe bí Mose ti wí, ó sáré lọ sí àárín àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti bẹ̀rẹ̀ láàrín wọn, ṣùgbọ́n Aaroni fín tùràrí, ó sì ṣe ètùtù fún wọn. Ó dúró láàrín àwọn alààyè àti òkú, àjàkálẹ̀-ààrùn náà sì dúró. Ṣùgbọ́n àjàkálẹ̀-ààrùn ti pa ẹgbàá-méje ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (14,700) ènìyàn ní àfikún sí àwọn tí ó kú níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Kora. Aaroni padà tọ Mose lọ ní ẹnu-ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé nítorí pé àjàkálẹ̀-ààrùn náà ti dúró.