Nehemiah 2:1-10

Nehemiah 2:1-10 YCB

Ní oṣù Nisani (oṣù kẹrin) ní ogún ọdún ìjọba ọba Artasasta, nígbà tí a gbé wáìnì wá fún un, mo gbé wáìnì náà mo fi fún ọba, ìbànújẹ́ kò hàn ní ojú mi rí ní iwájú rẹ̀. Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé “Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́? Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn.” Ẹ̀rù bà mí gidigidi, Ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Èéṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?” Ọba wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?” Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run, mo sì dá ọba lóhùn pé, “Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Juda níbi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́.” Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, “Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan. Mo sì tún wí fún ọba pé, “Bí ó bá wu ọba, kí ó fún mi ní lẹ́tà sí àwọn baálẹ̀ òkè odò Eufurate kí wọ́n le mú mi kọjá títí èmi yóò fi dé Juda láìléwu Kí èmi sì gba lẹ́tà kan lọ́wọ́ fún Asafu, olùṣọ́ igbó ọba, nítorí kí ó lè fún mi ní igi láti fi ṣe àtẹ́rígbà fún ibodè ilé ìṣọ́ tẹmpili àti fún odi ìlú náà àti fún ilé tí èmi yóò gbé?” Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi wà lórí mi, ọba fi ìbéèrè mi fún mi. Bẹ́ẹ̀ ni mo lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn baálẹ̀ agbègbè Eufurate, mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Ọba sì ti rán àwọn ológun àti àwọn ẹlẹ́ṣin ogun pẹ̀lú mi. Nígbà tí Sanballati ará Horoni àti Tobiah ará a Ammoni tí wọ́n jẹ́ ìjòyè gbọ́ nípa èyí pé, ẹnìkan wá láti mú ìtẹ̀síwájú bá àlàáfíà àwọn ará Israẹli inú bí wọn gidigidi.