Neh 2:1-10

Neh 2:1-10 YBCV

O si ṣe li oṣu Nisani, li ogún ọdun Artasasta ọba, ọti-waini wà niwaju rẹ̀: mo si gbe ọti-waini na, mo si fi fun ọba. Emi kò si ti ifajuro niwaju rẹ̀ rí. Nitorina ni ọba ṣe wi fun mi pe, ẽṣe ti oju rẹ fi faro? iwọ kò sa ṣaisan? eyi kì iṣe ohun miran bikoṣe ibanujẹ. Ẹ̀ru si ba mi gidigidi. Mo si wi fun ọba pe, Ki ọba ki o pẹ: ẽṣe ti oju mi kì yio fi faro, nigbati ilu, ile iboji awọn baba mi dahoro, ti a si fi iná sun ilẹkun rẹ̀? Nigbana ni ọba wi fun mi pe, ẹ̀bẹ kini iwọ fẹ bẹ̀? Bẹ̃ni mo gbadura si Ọlọrun ọrun. Mo si wi fun ọba pe, Bi o ba wù ọba, ati bi iranṣẹ rẹ ba ri ojurere lọdọ rẹ, ki iwọ le rán mi lọ si Juda, si ilu iboji awọn baba mi, ki emi ki o ba le kọ́ ọ. Ọba si wi fun mi pe, (ayaba si joko tì i) ajo rẹ yio ti pẹ to? nigbawo ni iwọ o si pada? Bẹli o wù ọba lati rán mi; mo si dá àkoko kan fun u. Pẹlupẹlu mo wi fun ọba pe, bi o ba wù ọba, ki o fun mi ni iwe si awọn bãlẹ li oke odò, ki nwọn le mu mi kọja titi emi o fi de Juda; Ati iwe kan fun Asafu, oluṣọ igbo ọba, ki o le fun mi ni igi fun atẹrigba ẹnu-ọ̀na odi lẹba ile Ọlọrun ati fun odi ilu, ati fun ile ti emi o wọ̀. Ọba si fun mi gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun mi lara mi. Nigbana ni mo de ọdọ awọn bãlẹ li oke odo mo si fi iwe ọba fun wọn: Ọba si ti rán awọn olori-ogun ati ẹlẹṣin pẹlu mi. Nigbati Sanballati ara Horoni ati Tobiah iranṣẹ ara Ammoni gbọ́, o bi wọn ni inu gidigidi pe, enia kan wá lati wá ire awọn ọmọ Israeli.