Lẹ́yìn náà, Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín. Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”
Nígbà tí Jesu sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa. Jesu béèrè wí pé, “Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà? Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́? Nítorí tí kò lọ sínú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n sínú ara, a sì yà á jáde, a sì gbá gbogbo oúnjẹ dànù.” (Nípa sísọ èyí, Jesu fihàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”)
Nígbà náà, ó fi kún un pé: “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọ ni di aláìmọ́. Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọtaraẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”
Nígbà náà ni Jesu kúrò ní Galili, ó sí lọ sí agbègbè Tire àti Sidoni, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri. Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jesu, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. Giriki ní obìnrin náà, Siro-Fonisia ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó bẹ Jesu kí ó bá òun lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun.
Jesu sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ èérún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábìlì.”
“Ó sì wí fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”
Nígbà tí ó padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.
Nígbà náà ni Jesu fi agbègbè Tire àti Sidoni sílẹ̀, ó wá si Òkun Galili láàrín agbègbè Dekapoli. Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, àwọn ènìyàn sì bẹ Jesu pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e.
Jesu sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ́ ṣọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀. Nígbà náà ni Jesu wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Efata!” (èyí ni, “Ìwọ ṣí!”). Lójúkan náà, etí rẹ̀ sì ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ketekete.
Jesu pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó. Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́rọ̀, odi sì sọ̀rọ̀.”