Mak 7:14-37
Mak 7:14-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà, Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín. Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.” Nígbà tí Jesu sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa. Jesu béèrè wí pé, “Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà? Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́? Nítorí tí kò lọ sínú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n sínú ara, a sì yà á jáde, a sì gbá gbogbo oúnjẹ dànù.” (Nípa sísọ èyí, Jesu fihàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”) Nígbà náà, ó fi kún un pé: “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọ ni di aláìmọ́. Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọtaraẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.” Nígbà náà ni Jesu kúrò ní Galili, ó sí lọ sí agbègbè Tire àti Sidoni, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri. Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jesu, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. Giriki ní obìnrin náà, Siro-Fonisia ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó bẹ Jesu kí ó bá òun lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun. Jesu sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.” Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ èérún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábìlì.” “Ó sì wí fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.” Nígbà tí ó padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀. Nígbà náà ni Jesu fi agbègbè Tire àti Sidoni sílẹ̀, ó wá si Òkun Galili láàrín agbègbè Dekapoli. Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, àwọn ènìyàn sì bẹ Jesu pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e. Jesu sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ́ ṣọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀. Nígbà náà ni Jesu wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Efata!” (èyí ni, “Ìwọ ṣí!”). Lójúkan náà, etí rẹ̀ sì ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì ń sọ̀rọ̀ ketekete. Jesu pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó. Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́rọ̀, odi sì sọ̀rọ̀.”
Mak 7:14-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o si pè gbogbo awọn enia sọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹ fi etí si mi olukuluku nyin, ẹ si kiyesi i: Kò si ohunkokun lati ode enia, ti o wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ti o le sọ ọ di alaimọ́: ṣugbọn nkan wọnni ti o ti inu rẹ̀ jade, awọn wọnni ni isọ enia di alaimọ́. Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́. Nigbati o si ti ọdọ awọn enia kuro wọ̀ inu ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre niti owe na. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin pẹlu wà li aimoye tobẹ̃? ẹnyin ko kuku kiyesi pe, ohunkohun ti o wọ̀ inu enia lati ode lọ, ko le sọni di alaimọ́; Nitoriti ko lọ sinu ọkàn rẹ̀, ṣugbọn sinu ara, a si yà a jade, a si gbá gbogbo onjẹ danù? O si wipe, Eyi ti o ti inu enia jade, eyini ni isọ enia di alaimọ́. Nitori lati inu, lati inu ọkàn enia ni iro buburu ti ijade wá, panṣaga, àgbere, ipania, Olè, ojukòkoro, iwa buburu, itanjẹ, wọ̀bia, oju buburu, isọrọ-odi, igberaga, iwère: Lati inu wá ni gbogbo nkan buburu wọnyi ti ijade, nwọn a si sọ enia di alaimọ́. O si dide ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni, o si wọ̀ inu ile kan, ko si fẹ ki ẹnikẹni ki o mọ̀: ṣugbọn on kò le fi ara pamọ́. Nitori obinrin kan, ẹniti ọmọbinrin rẹ̀ kekere li ẹmi aimọ́ gburo rẹ̀, o wá, o si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀: Hellene si li obinrin na, Sirofenikia ni orilẹ-ède rẹ̀; o si bẹ̀ ẹ ki on iba lé ẹmi èṣu na jade lara ọmọbinrin rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Jẹ ki a kọ́ fi onjẹ tẹ awọn ọmọ lọrun na: nitoriti ko tọ́ lati mu onjẹ awọn ọmọ, ki a si fi i fun ajá. O si dahùn o si wi fun u pe, Bẹni Oluwa: ṣugbọn awọn ajá pãpã a ma jẹ ẹrún awọn ọmọ labẹ tabili. O si wi fun u pe, Nitori ọ̀rọ yi, mã lọ; ẹmi ẹ̀ṣu na ti jade kuro lara ọmọbinrin rẹ. Nigbati o si pada wá si ile rẹ̀, o ri pe ẹmi èṣu na ti jade, ọmọbinrin rẹ̀ si sùn lori akete. O si tun lọ kuro li àgbegbe Tire on Sidoni, o wá si okun Galili larin àgbegbe Dekapoli. Nwọn si mu enia kan wá sọdọ rẹ̀ ti etí rẹ̀ di, ti o si nkólolo; nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o gbé ọwọ́ rẹ̀ le e. O si mu u kuro larin ijọ enia lọ si apakan, o si tẹ ika rẹ̀ bọ̀ ọ li etí, nigbati o tutọ́, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ li ahọn; O si gbé oju soke wo ọrun, o kẹdùn, o si wi fun u pe, Efata, eyini ni, Iwọ ṣí. Lojukanna, etì rẹ̀ si ṣí, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si nsọrọ ketekete. O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ fun ẹnikẹni: ṣugbọn bi o ti npaṣẹ fun wọn to, bẹ̃ ni nwọn si nkokikí rẹ̀ to; Ẹnu si yà wọn gidigidi rekọja, nwọn wipe, O ṣe ohun gbogbo daradara: o mu aditi gbọran, o si mu ki odi fọhun.
Mak 7:14-37 Yoruba Bible (YCE)
Ó tún pe àwọn eniyan, ó ń wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ fi etí sílẹ̀, kí ọ̀rọ̀ mi ye yín. Kò sí ohun kan láti òde wá tí ó wọ inú eniyan lọ tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́. Ṣugbọn àwọn ohun tí ó ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. [ Ẹni tí ó bá ní etí láti gbọ́ràn, kí ó gbọ́.”] Nígbà tí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, tí ó wọ inú ilé lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í ní ìtumọ̀ òwe yìí. Ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin náà kò ní òye? Kò ye yín pé kì í ṣe nǹkan tí ó bá wọ inú eniyan lọ níí sọ eniyan di aláìmọ́? Nítorí kì í wọ inú ọkàn lọ, bíkòṣe inú ikùn, a sì tún jáde.” (Báyìí ni ó pe gbogbo oúnjẹ ní mímọ́.) Ó tún fi kún un pé, “Àwọn nǹkan tí ń jáde láti inú eniyan ni ó ń sọ ọ́ di aláìmọ́. Nítorí láti inú ọkàn eniyan ni ète burúkú ti ń jáde: ìṣekúṣe, olè jíjà, ìpànìyàn, àgbèrè, ojúkòkòrò, ìwà ìkà, ẹ̀tàn, ìwà wọ̀bìà, owú jíjẹ, ọ̀rọ̀ ìṣáátá, ìwà ìgbéraga, ìwà òmùgọ̀. Láti inú ni gbogbo àwọn nǹkan ibi wọnyi ti ń wá, àwọn ni ó ń sọ eniyan di aláìmọ́.” Láti ibẹ̀ Jesu gbéra, ó lọ sí agbègbè ìlú Tire, ó sì wọ̀ sí ilé kan. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, ṣugbọn kò lè fi ara pamọ́. Obinrin kan tí ọdọmọbinrin rẹ̀ ní ẹ̀mí èṣù gbọ́ nípa rẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ó wá kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ọmọ ìbílẹ̀ Giriki ni obinrin yìí, a bí i ní Fonike ní Siria. Ó ń bẹ̀ ẹ́ kí ó lé ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọdọmọbinrin òun. Jesu wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ rí oúnjẹ jẹ yó ná, nítorí kò dára kí á mú oúnjẹ ọmọ kí á sọ ọ́ fún ajá.” Ṣugbọn obinrin náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, alàgbà, ṣugbọn àwọn ajá a máa jẹ ẹ̀rúnrún oúnjẹ àwọn ọmọ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tabili.” Jesu dá a lóhùn pé, “Nítorí gbolohun rẹ yìí, máa lọ sí ilé rẹ, ẹ̀mí èṣù náà ti jáde kúrò ninu ọmọ rẹ.” Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀, ó rí ọmọde náà tí ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn, tí ẹ̀mí burúkú náà ti jáde kúrò lára rẹ̀. Ó tún jáde kúrò ní agbègbè ìlú Tire, ó la ìlú Sidoni kọjá lọ sí òkun Galili ní ọ̀nà ààrin Ìlú Mẹ́wàá. Wọ́n wá gbé adití kan tí ń kólòlò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ lé e. Ó bá mú un bọ́ sí apá kan, kúrò láàrin àwọn ọ̀pọ̀ eniyan, ó ti ìka rẹ̀ bọ ọkunrin náà létí, ó tutọ́, ó fi kan ahọ́n rẹ̀. Ó gbé ojú sí òkè ọ̀run, ó kẹ́dùn, ó bá ní, “Efata,” ìtumọ̀ èyí tí i ṣe, “Ìwọ, ṣí.” Etí ọkunrin náà bá ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀ gaara. Jesu kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má wí fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn bí ó ti ń kìlọ̀ fún wọn tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ròyìn rẹ̀ tó. Ẹnu ya gbogbo wọn kọjá ààlà, wọ́n ń wí pé, “Ó ṣe ohun gbogbo dáradára: ó mú kí adití gbọ́ràn, ó mú kí odi sọ̀rọ̀.”