Marku 4:26-34

Marku 4:26-34 YCB

Ó sì tún sọ èyí pé, “Èyí ni a lè fi ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀. Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀. Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ní orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó. Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.” Jesu sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀? Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.” Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó. Kìkì òwe ni Jesu fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.

Àwọn fídíò fún Marku 4:26-34