O si wipe, Bẹ̃ sá ni ijọba Ọlọrun, o dabi ẹnipe ki ọkunrin kan funrugbin sori ilẹ; Ki o si sùn, ki o si dide li oru ati li ọsán, ki irugbin na ki o si sọ jade ki o si dàgba, on kò si mọ̀ bi o ti ri. Nitori ilẹ a ma so eso jade fun ara rẹ̀; ekini ẽhù, lẹhinna ipẹ́, lẹhinna ikunmọ ọkà ninu ipẹ́. Ṣugbọn nigbati eso ba pọ́n tan, lojukanna on a tẹ̀ doje bọ inu rẹ̀ nitori igba ikorè de. O si wipe, Kili a o fi ijọba Ọlọrun we? tabi kili a ba fi ṣe akawe rẹ̀? O dabi wóro irugbin mustardi, eyiti, nigbati a gbin i si ilẹ, bi o tilẹ ṣe pe o kére jù gbogbo irugbin ti o wa ni ilẹ lọ, Sibẹ nigbati a gbin i o dàgba soke, o si di titobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si pa ẹká nla; tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun le ma gbe abẹ ojiji rẹ̀. Irù ọ̀pọ owe bẹ̃ li o fi mba wọn nsọ̀rọ, niwọn bi nwọn ti le gbà a si. Ṣugbọn on kì iba wọn sọrọ laìsi owe: nigbati o ba si kù awọn nikan, on a si sọ idi ohun gbogbo fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
Kà Mak 4
Feti si Mak 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 4:26-34
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò