Matiu 6:5-14

Matiu 6:5-14 YCB

“Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní Sinagọgu àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ìlẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ. Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. “Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín, Kí ìjọba yín dé, Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe ní ayé bí ti ọ̀run. Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí Ẹ dárí gbèsè wa jì wá, Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa, Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò, Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi. Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’ Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí jí àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dáríjì yín.

Àwọn fídíò fún Matiu 6:5-14

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Matiu 6:5-14

Matiu 6:5-14 - “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe ṣe bí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọn fẹ́ràn láti máa dúró gbàdúrà ní Sinagọgu àti ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà tí ènìyàn ti lè rí wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ní kíkún. Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, wọ inú iyàrá rẹ lọ, sé ìlẹ̀kùn mọ́ ara rẹ, gbàdúrà sí Baba rẹ ẹni tí ìwọ kò rí. Nígbà náà ni Baba rẹ tí ó mọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ rẹ, yóò san án fún ọ. Ṣùgbọ́n nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán bí àwọn aláìkọlà, nítorí wọn rò pé a ó tìtorí ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ gbọ́ tiwọn. Ẹ má ṣe dàbí i wọn, nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ ohun tí ẹ ṣe aláìní, kí ẹ tilẹ̀ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
“Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ ṣe máa gbàdúrà:
“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,
ọ̀wọ̀ fún orúkọ yín,
Kí ìjọba yín dé,
Ìfẹ́ tiyín ni kí a ṣe
ní ayé bí ti ọ̀run.
Ẹ fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí
Ẹ dárí gbèsè wa jì wá,
Bí àwa ti ń dáríji àwọn ajigbèsè wa,
Ẹ má ṣe fà wá sínú ìdánwò,
Ṣùgbọ́n ẹ gbà wá lọ́wọ́ ibi.
Nítorí ìjọba ni tiyín, àti agbára àti ògo, láéláé, Àmín.’
Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá dárí jí àwọn tó ṣẹ̀ yín, baba yín ọ̀run náà yóò dáríjì yín.