Matiu 26:47-68

Matiu 26:47-68 YCB

Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà Júù wá. Ẹni tí ó sì fi í hàn ti fi ààmì fún wọn, pé, “Ẹnikẹ́ni tí mo bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun náà ni; ẹ mú un.” Nísinsin yìí, Judasi wá tààrà sọ́dọ̀ Jesu, ó wí pé, “Àlàáfíà, Rabbi” ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu. Jesu wí pé, “Ọ̀rẹ́, kí ni nǹkan tí ìwọ bá wá.” Àwọn ìyókù sì sún síwájú wọ́n sì mú Jesu. Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jesu na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì sá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù. Jesu wí fún un pé, “Fi idà rẹ bọ àkọ̀ nítorí àwọn tí ó ń fi idà pa ni a ó fi idà pa. Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì (6,000) angẹli méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsin yìí?” Nígbà náà ni Jesu wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Ǹjẹ́ èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹmpili, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà. Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn tí ó mú Jesu fà á lọ sí ilé Kaiafa, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbàgbà Júù péjọ sí. Ṣùgbọ́n Peteru ń tẹ̀lé e lókèèrè. Òun sì wá sí àgbàlá olórí àlùfáà. Ó wọlé, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùṣọ́. Ó ń dúró láti ri ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Jesu. Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ Júù ní ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ti Júù péjọ síbẹ̀, wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí tí yóò purọ́ mọ́ Jesu, kí a ba à lè rí ẹjọ́ rò mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, eléyìí tí yóò yọrí si ìdájọ́ ikú fún un. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́rìí èké dìde, ṣùgbọ́n wọn kò rí ohun kan. Níkẹyìn, àwọn ẹlẹ́rìí méjì dìde. Wọn wí pé, “Ọkùnrin yìí sọ pé, ‘Èmi lágbára láti wó tẹmpili Ọlọ́run lulẹ̀, èmi yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ mẹ́ta.’ ” Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jesu pé, “Ẹ̀rí yìí ńkọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?” Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́. Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè: Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.” Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.” Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tìkára rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀-òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?” Ki ni ẹ ti rò èyí sí. Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!” Wọ́n tu itọ́ sí i ní ojú. Wọ́n kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Àwọn ẹlòmíràn sì gbá a lójú. Wọ́n wí pé, “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún wa! Ìwọ Kristi, Ta ni ẹni tí ó ń lù Ọ́?”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ