Bi o si ti nsọ lọwọ, wo o, Judasi, ọkan ninu awọn mejila de, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà pẹlu ọgọ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá.
Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu ko li ẹnu, on na ni: ẹ mú u.
Lojukanna o wá sọdọ Jesu, o si wipe, Alafia, Olukọni; o si fi ẹnu ko o li ẹnu.
Jesu si wi fun u pe, Ọrẹ́, nitori kini iwọ fi wá? Nigbana ni nwọn wá, nwọn si gbé ọwọ́ le Jesu, nwọn si mu u.
Si wo o, ọkan ninu awọn ti o wà pẹlu Jesu nà ọwọ́ rẹ̀, o si fà idà rẹ̀ yọ, o si ṣá ọkan ti iṣe ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke e li etí sọnù.
Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Fi idà rẹ si ipò rẹ̀: nitoripe gbogbo awọn ti o mu idà ni yio ti ipa idà ṣegbé.
Iwọ ṣebi emi ko le kepè Baba mi, on iba si fun mi jù legioni angẹli mejila lọ lojukanna yi?
Ṣugbọn iwe-mimọ́ yio ha ti ṣe ti yio fi ṣẹ, pe bẹ̃ni yio ri?
Ni wakati na ni Jesu wi fun ijọ enia pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu? li ojojumọ li emi mba nyin joko ni tẹmpili ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si gbé ọwọ́ le mi.
Ṣugbọn gbogbo eyi ṣe, ki iwe-mimọ́ awọn wolĩ ba le ṣẹ. Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ fi i silẹ, nwọn si sá lọ.
Awọn ti o si mu Jesu, fà a lọ si ile Kaiafa, olori alufa, nibiti awọn akọwe ati awọn agbàgba gbé pejọ si.
Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ́ lẹhin li òkere titi fi de agbala olori alufa, o bọ́ si ile, o si bá awọn ọmọ-ọdọ na joko lati ri opin rẹ̀.
Nigbana li olori alufa, ati awọn alàgba, ati gbogbo ajọ igbimọ nwá ẹlẹri eke si Jesu lati pa a;
Ṣugbọn nwọn ko ri ohun kan: otitọ li ọ̀pọ ẹlẹri eke wá, ṣugbọn nwọn kò ri ohun kan. Nikẹhin li awọn ẹlẹri eke meji wá;
Nwọn wipe, ọkunrin yi wipe, Emi le wó tẹmpili Ọlọrun, emi o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta.
Olori alufa si dide, o si wi fun u pe, Iwọ ko dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ?
Ṣugbọn Jesu dakẹ. Olori alufa dahùn o si wi fun u pe, Mo fi Ọlọrun alãye bẹ̀ ọ pé, ki iwọ ki o sọ fun wa bi iwọ ba ṣe Kristi Ọmọ Ọlọrun.
Jesu wi fun u pe, Iwọ wi i: ṣugbọn mo wi fun nyin, Lẹhin eyi li ẹnyin o ri Ọmọ-enia ti yio joko li ọwọ́ ọtún agbara, ti yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá.
Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, O sọ ọrọ-odi; ẹlẹri kili a si nwá? wo o, ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na nisisiyi.
Ẹnyin ti rò o si? Nwọn dahùn, wipe, O jẹbi ikú.
Nigbana ni nwọn tutọ́ si i loju, nwọn kàn a lẹṣẹ́; awọn ẹlomiran fi atẹ́lọwọ́ wọn gbá a loju;
Nwọn wipe, Sọtẹlẹ fun wa, iwọ, Kristi, tali ẹniti o nlù ọ ni?