Luku 6:27-49

Luku 6:27-49 YCB

“Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi: Ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín; Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín. Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, yí kejì sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú. Sì fi fún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ ní ẹrù, má sì ṣe padà béèrè. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn ṣe sí yín, kí ẹ̀yin sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú. “Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn. Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́ṣẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú. “Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dá ni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín. Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.” Ó sì pa òwe kan fún wọn wí pé, “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí? Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ dáradára, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀. “Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ lójú rẹ,’ nígbà tí ìwọ tìkára rẹ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò. “Nítorí igi rere kì í so èso búburú; bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere. Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn; nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èso ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èso àjàrà. Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde. “Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí? Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín; Ó jọ Ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi kọlu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì ṣe é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi kọlù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”

Àwọn fídíò fún Luku 6:27-49

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Luku 6:27-49

Luku 6:27-49 - “Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi: Ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín; Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín. Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, yí kejì sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú. Sì fi fún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ ní ẹrù, má sì ṣe padà béèrè. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn ṣe sí yín, kí ẹ̀yin sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú.
“Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn. Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́ṣẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.

“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dá ni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín. Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.”
Ó sì pa òwe kan fún wọn wí pé, “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí? Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ dáradára, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.
“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ lójú rẹ,’ nígbà tí ìwọ tìkára rẹ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò.

“Nítorí igi rere kì í so èso búburú; bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere. Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn; nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èso ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èso àjàrà. Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde.

“Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí? Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín; Ó jọ Ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi kọlu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì ṣe é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi kọlù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”Luku 6:27-49 - “Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi: Ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín; Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín. Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, yí kejì sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú. Sì fi fún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ ní ẹrù, má sì ṣe padà béèrè. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn ṣe sí yín, kí ẹ̀yin sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú.
“Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn. Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́ṣẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.

“Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dá ni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín. Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.”
Ó sì pa òwe kan fún wọn wí pé, “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí? Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ dáradára, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.
“Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ lójú rẹ,’ nígbà tí ìwọ tìkára rẹ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò.

“Nítorí igi rere kì í so èso búburú; bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere. Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn; nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èso ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èso àjàrà. Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde.

“Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí? Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín; Ó jọ Ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi kọlu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì ṣe é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi kọlù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”