Luk 6:27-49
Luk 6:27-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ṣùgbọ́n mo wí fún ẹ̀yin tí ń gbọ́ mi: Ẹ fẹ́ àwọn ọ̀tá yín, ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín; Súre fún àwọn tí ń fi yín ré, sì gbàdúrà fún àwọn tí ń kẹ́gàn yín. Ẹni tí ó bá sì lù ọ́ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ kan, yí kejì sí i pẹ̀lú; àti ẹni tí ó gba agbádá rẹ, má ṣe dá a dúró láti gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ pẹ̀lú. Sì fi fún gbogbo ẹni tí ó tọrọ lọ́dọ̀ rẹ; lọ́dọ̀ ẹni tí ó sì kó ọ ní ẹrù, má sì ṣe padà béèrè. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti fẹ́ kí ènìyàn ṣe sí yín, kí ẹ̀yin sì ṣe bẹ́ẹ̀ sí wọn pẹ̀lú. “Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin bá fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ yín, ọpẹ́ kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń fẹ́ àwọn tí ó fẹ́ wọn. Bí ẹ̀yin sì ṣoore fún àwọn tí ó ṣoore fún yín, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ‘ẹlẹ́ṣẹ̀’ pẹ̀lú ń yá ‘ẹlẹ́ṣẹ̀,’ kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú. “Ẹ má ṣe dá ni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dá ni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín. Ẹ fi fún ni, a ó sì fi fún yín; òṣùwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ́n si àyà yín: nítorí òṣùwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ́n, òun ni a ó padà fi wọ́n fún yín.” Ó sì pa òwe kan fún wọn wí pé, “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí? Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí a bá kọ dáradára, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀. “Èétiṣe tí ìwọ fi ń wo ẹ̀rún igi tí ń bẹ ní ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ ní ojú ara rẹ? Tàbí ìwọ ó ti ṣe lè wí fún arákùnrin rẹ pé, ‘Arákùnrin, jẹ́ kí èmi yọ ẹ̀rún igi tí ń bẹ lójú rẹ,’ nígbà tí ìwọ tìkára rẹ kò kíyèsi ìtì igi tí ń bẹ lójú rẹ? Ìwọ àgàbàgebè, kọ́kọ́ yọ ìtí igi jáde kúrò lójú ara rẹ ná, nígbà náà ni ìwọ ó sì tó ríran gbangba láti yọ èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ kúrò. “Nítorí igi rere kì í so èso búburú; bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kì í so èso rere. Olúkúlùkù igi ni a ń fi èso rẹ̀ mọ̀ ọn; nítorí lórí ẹ̀gún òṣùṣú, ènìyàn kì í ká èso ọ̀pọ̀tọ́ bẹ́ẹ̀ ni lórí ẹ̀gún ọ̀gàn a kì í ká èso àjàrà. Ènìyàn rere láti inú yàrá ìṣúra rere ọkàn rẹ̀ ní mú ohun rere jáde wá; àti ènìyàn búburú láti inú ìṣúra búburú ọkàn rẹ̀ ní í mú ohun búburú jáde wá: nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọkàn ní ẹnu ti máa sọ jáde. “Nítorí náà, èéṣe tí ẹ̀yin ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ tí ẹ̀yin kò sì ṣe ohun tí mo wí? Ẹnikẹ́ni tí ó tọ̀ mí wá, tí ó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ń ṣe é, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín; Ó jọ Ọkùnrin kan, tí ó kọ́ ilé, tí ó sì wa ilẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta, nígbà tí kíkún omi sì dé, ìgbì omi kọlu ilé náà, kò sì lè mì ín nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ lórí àpáta. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́, tí kò sì ṣe é, ó dàbí ọkùnrin tí ó kọ́ ilé sí orí ilẹ̀ láìní ìpìlẹ̀; nígbà tí ìgbì omi kọlù ú, lọ́gán, ó sì wó; wíwó ilé náà sì pọ̀ púpọ̀.”
Luk 6:27-49 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn mo wi fun ẹnyin ti ngbọ́, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ṣore fun awọn ti o korira nyin. Sure fun awọn ti nfi nyin ré, si gbadura fun awọn ti nkẹgan nyin. Ẹniti o ba si lù ọ ni ẹrẹkẹ kan, pa ekeji dà si i pẹlu; ati ẹniti o gbà agbada rẹ, máṣe da a duro lati gbà àwọtẹlẹ rẹ pẹlu. Si fifun gbogbo ẹniti o tọrọ lọdọ rẹ; lọdọ ẹniti o si kó ọ li ẹrù, má si ṣe pada bère. Gẹgẹ bi ẹnyin si ti fẹ ki enia ki o ṣe si nyin, ki ẹnyin ki o si ṣe bẹ̃ si wọn pẹlu. Njẹ bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nfẹ́ awọn ti o fẹ wọn. Bi ẹnyin si ṣore fun awọn ti o ṣore fun nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nṣe bẹ̃ gẹgẹ. Bi ẹnyin si win wọn ni nkan lọwọ ẹniti ẹnyin ó reti ati ri gbà pada, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? awọn ẹlẹṣẹ pẹlu nwin ẹlẹṣẹ, ki nwọn ki o le gbà iwọn bẹ̃ pada. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fẹ awọn ọtá nyin, ki ẹnyin ki o si ṣore, ki ẹnyin ki o si winni, ki ẹnyin ki o máṣe reti ati ri nkan gbà pada; ère nyin yio si pọ̀, awọn ọmọ Ọgá-ogo li a o si ma pè nyin: nitoriti o ṣeun fun alaimore ati fun ẹni-buburu. Njẹ ki ẹnyin ki o li ãnu, gẹgẹ bi Baba nyin si ti li ãnu. Ẹ máṣe dani li ẹjọ, a kì yio si da nyin li ẹjọ: ẹ máṣe dani li ẹbi, a kì yio si da nyin li ẹbi: ẹ darijì, a o si darijì nyin: Ẹ fifun ni, a o si fifun nyin; oṣuwọn daradara, akìmọlẹ, ati amipọ, akún-wọsilẹ, li a o wọ̀n si àiya nyin; nitori oṣuwọn na ti ẹnyin fi wọ̀n, on li a o pada fi wọ̀n fun nyin. O si pa owe kan fun wọn, Afọju le ṣe amọ̀na afọju? awọn mejeji kì yio ṣubu sinu ihò? Ẹniti a nkọ́ ki ijù olukọ́ rẹ̀ lọ: ṣugbọn olukuluku ẹniti o ba pé, yio dabi olukọ́ rẹ̀. Ẽṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? Tabi iwọ o ti ṣe le wi fun arakunrin rẹ pe, Arakunrin, jẹ ki emi ki o yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, nigbati iwọ tikararẹ kò kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? iwọ agabagebe, tètekọ yọ ìti igi jade kuro li oju ara rẹ na, nigbana ni iwọ o si to riran gbangba lati yọ ẹrún igi kuro ti mbẹ li oju arakunrin rẹ. Nitori igi rere kì iso eso buburu; bẹ̃ni igi buburu kì iso eso rere. Olukuluku igi li a ifi eso rẹ̀ mọ̀; nitori lori ẹgún oṣuṣu, enia kì iká eso ọpọtọ bẹ̃ni lori ẹgún ọgàn a kì iká eso ajara. Enia rere lati inu iṣura rere ọkàn rẹ̀ ni imu ohun rere jade wá; ati enia buburu lati inu iṣura buburu ọkàn rẹ̀ ni imu ohun buburu jade wá: nitori lati ọ̀pọlọpọ ohun ọkàn li ẹnu rẹ̀ isọ. Ẽsitiṣe ti ẹnyin npè mi li Oluwa, Oluwa, ti ẹnyin kò si ṣe ohun ti mo wi? Ẹnikẹni ti o tọ̀ mi wá, ti o si ngbọ́ ọ̀rọ mi, ti o si nṣe e, emi o fi ẹniti o jọ hàn nyin: O jọ ọkunrin kan ti o kọ́ ile, ti o si walẹ jìn, ti o si fi ipilẹ sọlẹ lori apata: nigbati kíkun omi de, igbi-omi bilù ile na, kò si le mì i: nitoriti a fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ lori apata. Ṣugbọn ẹniti o gbọ́, ti kò si ṣe, o dabi ọkunrin ti o kọ́ ile si ori ilẹ laini ipilẹ; nigbati igbi-omi bilù u, lọgan o si wó; iwó ile na si pọ̀.
Luk 6:27-49 Yoruba Bible (YCE)
“Ṣugbọn fún ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, mo sọ fun yín pé: ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín: ẹ máa ṣoore fún àwọn tí ó kórìíra yín. Ẹ máa súre fún àwọn tí ó ń gbe yín ṣépè. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí wọn ń ṣe àìdára si yín. Bí ẹnìkan bá gba yín létí, ẹ yí ẹ̀gbẹ́ keji sí i. Ẹni tí ó bá gba agbádá yín, ẹ má ṣe du dàńṣíkí yín mọ́ ọn lọ́wọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá tọrọ nǹkan lọ́wọ́ yín, ẹ fún un. Bí ẹnìkan bá mú nǹkan yín, ẹ má bèèrè rẹ̀ pada. Bí ẹ bá ti fẹ́ kí eniyan máa ṣe si yín, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ máa ṣe sí wọn. “Bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan ni ẹ fẹ́ràn kí ni fáàrí yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ràn wọn. Bí ẹ bá ń ṣe rere sí àwọn tí wọn ń ṣe rere si yín, kí ni fáàrí yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń ṣe bẹ́ẹ̀. Bí ẹ bá yá eniyan lówó tí ó jẹ́ ẹni tí ẹ nírètí pé yóo san án pada, kí ni fáàrí yín. Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá ń yá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ẹgbẹ́ wọn lówó kí wọn lè rí i gbà pada ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ṣugbọn ẹ máa fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín; ẹ ṣoore. Ẹ máa yá eniyan lówó láì ní ìrètí láti gbà á pada. Èrè yín yóo pọ̀, ẹ óo wá jẹ́ ọmọ Ọ̀gá Ògo nítorí ó ń ṣoore fún àwọn aláìmoore ati àwọn eniyan burúkú. Ẹ jẹ́ aláàánú gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú. “Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́jọ́, kí Ọlọrun má baà dá ẹ̀yin náà lẹ́jọ́. Ẹ má ṣe dá eniyan lẹ́bi. Ẹ máa dáríjì eniyan, Ọlọrun yóo sì dáríjì yín. Ẹ máa fún eniyan lẹ́bùn, Ọlọrun yóo sì fun yín ní ẹ̀bùn. Òṣùnwọ̀n rere, tí a kì tí ó kún, tí a mì dáradára, tí ó kún tí ó ń ṣàn sílẹ̀ ni a óo fi wọ̀n ọ́n le yín lọ́wọ́. Nítorí òṣùnwọ̀n tí ẹ bá lò fún ẹlòmíràn ni a óo lò fun yín.” Jesu wá tún pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Afọ́jú kò lè fi ọ̀nà han afọ́jú. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú kòtò ni àwọn mejeeji yóo bá ara wọn. Ọmọ-ẹ̀yìn kò ju olùkọ́ rẹ̀ lọ. Ṣugbọn bí ọmọ-ẹ̀yìn bá jáfáfá yóo dàbí olùkọ́ rẹ̀. “Kí ló dé tí o fi ń wo ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ, nígbà tí o kò ṣe akiyesi ìtì igi ńlá tí ó wà lójú ìwọ alára? Báwo ni o ṣe lè wí fún arakunrin rẹ pé, ‘Ọ̀rẹ́, jẹ́ kí n bá ọ yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú rẹ,’ nígbà tí o kò rí ìtì igi tí ó wà lójú ara rẹ? Ìwọ a-rí-tẹni-mọ̀-ọ́n-wí, kọ́kọ́ yọ ìtì igi kúrò lójú ara rẹ, nígbà náà, ìwọ óo ríran kedere láti lè yọ ẹ̀ẹ́rún igi tí ó wà lójú arakunrin rẹ. “Igi rere kò lè so èso burúkú. Bẹ́ẹ̀ ni igi burúkú kò lé so èso rere. Èso tí igi kan bá so ni a óo fi mọ̀ ọ́n. Nítorí eniyan kò lè ká èso ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi ẹlẹ́gùn-ún. Bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò lè rí èso ọsàn lórí igi ọdán. Eniyan rere ń mú ohun rere wá láti inú orísun rere ọkàn rẹ̀. Eniyan burúkú ń mú nǹkan burúkú jáde láti inú ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí ohun tí ó bá wà ninu ọkàn ẹni ni ẹnu ẹni ń sọ jáde. “Kí ló dé tí ẹ̀ ń pè mí ní, ‘Oluwa, Oluwa,’ tí ẹ kì í ṣe ohun tí mo sọ? Ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí ó ń ṣe é, n óo sọ fun yín ẹni tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ jọ. Ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé, tí ó wa ìpìlẹ̀ rẹ̀ tí ó jìn, tí ó wá fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé orí àpáta. Nígbà tí ìkún omi dé, tí àgbàrá bì lu ilé náà, kò lè mì ín, nítorí wọ́n kọ́ ọ dáradára. Ṣugbọn ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí kò ṣe é, ó dàbí ọkunrin kan tí ó ń kọ́ ilé kalẹ̀ láì ní ìpìlẹ̀. Nígbà tí àgbàrá bì lù ú, lẹsẹkẹsẹ ni ó wó, ó sì wó kanlẹ̀ patapata.”