Luku 3:16-22

Luku 3:16-22 YCB

Johanu dáhùn ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Lóòótọ́ ni èmi ń fi omi bamitiisi yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú: òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín: Ẹni tí àtẹ rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, láti gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ mọ́ tó tó, kí ó sì kó alikama rẹ̀ sínú àká; ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.” Johanu lo oríṣìíríṣìí ọ̀rọ̀ púpọ̀ láti gba àwọn ènìyàn níyànjú àti láti wàásù ìhìnrere fún wọn. Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe, Ó fi èyí parí gbogbo rẹ̀ nígba tí ó fi Johanu sínú túbú. Nígbà tí a ṣe ìtẹ̀bọmi àwọn ènìyàn gbogbo tán, ó sì ṣe, a bamitiisi Jesu pẹ̀lú, bí ó ti ń gbàdúrà, ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sì sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ ní àwọ̀ àdàbà, ohùn kan sì ti ọ̀run wá, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi; ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

Àwọn fídíò fún Luku 3:16-22