Luk 3:16-22

Luk 3:16-22 YBCV

Johanu dahùn o si wi fun gbogbo wọn pe, Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin; ṣugbọn ẹniti o lagbarà ju mi lọ mbọ̀, okùn bàta ẹsẹ ẹniti emi ko to itú: on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin: Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, lati gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, ki o si kó alikama rẹ̀ sinu aká; ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun. Ohun pipọ pẹlu li o si wasu fun awọn enia ni ọrọ iyanju rẹ̀. Ṣugbọn Herodu tetrarki, ti o bawi nitori Herodia aya Filippi arakunrin rẹ̀, ati nitori ohun buburu gbogbo ti Herodu ti ṣe, O fi eyi pari gbogbo rẹ̀ niti o fi Johanu sinu tubu. Nigbati a si baptisi awọn enia gbogbo tan, o si ṣe, a baptisi Jesu pẹlu, bi o ti ngbadura, ọrun ṣí silẹ̀, Ẹmí Mimọ́ si sọkalẹ si ori rẹ̀ li àwọ àdaba, ohùn kan si ti ọrun wá, ti o wipe, Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹniti inu mi dùn si gidigidi.

Àwọn fídíò fún Luk 3:16-22