Luku 20:27-47

Luku 20:27-47 YCB

Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í, wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ. Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú. Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú. Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.” Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni. Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni. Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde. Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.” Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!” Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́. Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dafidi ni Kristi? Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé: “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’ Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè; Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”

Àwọn fídíò fún Luku 20:27-47