Luk 20:27-47

Luk 20:27-47 Bibeli Mimọ (YBCV)

Awọn Sadusi kan si tọ̀ ọ wá, awọn ti nwọn nwipe ajinde okú kò si: nwọn si bi i, Wipe, Olukọni, Mose kọwe fun wa pe, Bi arakunrin ẹnikan ba kú, li ailọmọ, ti o li aya, ki arakunrin rẹ̀ ki o ṣu aya rẹ̀ lopó, ki o le gbe iru dide fun arakunrin rẹ̀. Njẹ awọn arakunrin meje kan ti wà: ekini gbé iyawo, o si kú li ailọmọ. Ekeji si ṣu u lopó, on si kú li ailọmọ. Ẹkẹta si ṣu u lopó; gẹgẹ bẹ̃ si li awọn mejeje pẹlu: nwọn kò si fi ọmọ silẹ, nwọn si kú. Nikẹhin gbogbo wọn, obinrin na kú pẹlu. Njẹ li ajinde okú, aya titani yio ha ṣe ninu wọn? nitori awọn mejeje li o sá ni i li aya. Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Awọn ọmọ aiye yi a ma gbeyawo, nwọn a si ma fà iyawo fun-ni. Ṣugbọn awọn ti a kà yẹ lati jogún aiye na, ati ajinde kuro ninu okú, nwọn kì igbeyawo, nwọn kì si ifà iyawo fun-ni: Nitori nwọn kò le kú mọ́; nitoriti nwọn ba awọn angẹli dọgba; awọn ọmọ Ọlọrun si ni nwọn, nitori nwọn di awọn ọmọ ajinde. Niti pe a njí awọn okú dide, Mose tikararẹ̀ si ti fihàn ni igbẹ́, nigbati o pè Oluwa ni Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Bẹni on kì iṣe Ọlọrun awọn okú, bikoṣe ti awọn alãye: nitori gbogbo wọn wà lãye fun u. Nigbana li awọn kan ninu awọn akọwe da a lohùn, wipe, Olukọni iwọ wi rere. Nwọn kò si jẹ bi i lẽre òrọ kan mọ́. O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti nwọn fi nwipe, Ọmọ Dafidi ni Kristi? Dafidi tikararẹ̀ si wi ninu iwe Psalmu pe, OLUWA wi fun Oluwa mi pe, Iwọ joko li ọwọ́ ọtún mi, Titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ. Njẹ bi Dafidi ba pè e li Oluwa; on ha si ti ṣe jẹ ọmọ rẹ̀? O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li etí gbogbo enia pe, Ẹ mã kiyesara lọdọ awọn akọwe, ti nwọn fẹ lati mã rìn li aṣọ gigùn, ti nwọn si fẹ ikí-ni li ọjà, ati ibujoko ọlá ninu sinagogu, ati ipò ọla ni ibi àse; Awọn ti o jẹ ile awọn opó run, ti nwọn si ngbadura gìgun fun aṣehàn: awọn wọnyi na ni yio jẹbi pọ̀ju.

Luk 20:27-47 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn kan ninu àwọn Sadusi bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. (Àwọn Sadusi ni wọn kò gbà pé òkú kan a tún máa jinde.) Wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, Mose pàṣẹ fún wa pé bí eniyan bá ní iyawo, bí ó bá kú láìní ọmọ, kí àbúrò rẹ̀ ṣú iyawo rẹ̀ lópó, kí ó ní ọmọ lórúkọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà. Ekinni gbé iyawo, ó kú láìní ọmọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni ekeji. Ẹkẹta náà ṣú u lópó. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mejeeje ṣe, wọ́n kú láì ní ọmọ. Ní ìgbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obinrin náà alára wá kú. Ní ọjọ́ ajinde, ti ta ni obinrin náà yóo jẹ́, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn mejeeje ló ti fi ṣe aya?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn eniyan ayé yìí ni wọ́n ń gbeyawo, tí wọn ń fi ọmọ fọ́kọ. Ṣugbọn àwọn tí a kà yẹ fún ayé tí ó ń bọ̀, nígbà tí àwọn òkú bá jinde, kò ní máa gbeyawo, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní máa fọmọ fọ́kọ. Nítorí wọn kò lè kú mọ́, nítorí bákan náà ni wọ́n rí pẹlu àwọn angẹli. Ọmọ Ọlọrun ni wọ́n, nítorí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ajinde. Ó dájú pé a jí àwọn òkú dìde nítorí ohun tí Mose kọ ninu ìtàn ìgbẹ́ tí ń jóná, nígbà tí ó sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun ti Jakọbu.’ Ọlọrun kì í ṣe Ọlọrun àwọn òkú, ti àwọn alààyè ni; nítorí pé gbogbo wọn ni ó wà láàyè fún Ọlọrun.” Àwọn kan ninu àwọn amòfin dá a lóhùn pé, “Olùkọ́ni, o wí ire!” Láti ìgbà náà kò tún sí ẹni tí ó láyà láti bi í ní nǹkankan mọ́. Jesu bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni wọ́n ṣe ń pe Mesaya ní ọmọ Dafidi? Nítorí Dafidi sọ ninu ìwé Orin Dafidi pé, ‘Oluwa wí fún oluwa mi pé: Jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.’ Nígbà tí Dafidi pè é ní Oluwa, báwo ni ó ti ṣe tún jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Ní etí gbogbo àwọn eniyan, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ máa wọ agbádá ńlá. Wọ́n tún gbádùn kí eniyan máa kí wọn ní ààrin ọjà. Wọ́n fẹ́ràn láti jókòó níwájú ninu ilé ìpàdé ati láti jókòó ní ipò ọlá níbi àsè. Wọn a máa jẹ ilé àwọn opó run. Wọ́n a máa gba adura gígùn láti ṣe àṣehàn. Wọn yóo gba ìdájọ́ líle.”

Luk 20:27-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í, wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀. Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ. Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú. Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú. Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.” Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni. Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni. Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde. Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.” Nígbà náà ni àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé dá a lóhùn, pé, “Olùkọ́ ìwọ wí rere!” Wọn kò sì jẹ́ bi í léèrè ọ̀rọ̀ kan mọ́. Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí wọ́n fi ń wí pé, Ọmọ Dafidi ni Kristi? Dafidi tìkára rẹ̀ sì wí nínú ìwé Saamu pé: “ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé: “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi ó fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’ Ǹjẹ́ bí Dafidi bá pè é ní ‘Olúwa.’ Òun ha sì ti ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?” Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè; Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”