OLúWA sọ fún Mose pé. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ẹnìkan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì láti ya ènìyàn kan sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run nípa sísan iye tí ó tó, kí iye owó ọkùnrin láti ọmọ ogún ọdún sí ọgọ́ta ọdún jẹ́ àádọ́ta òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà, gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ṣékélì ti ibi mímọ́ OLúWA; Bí ẹni náà bá jẹ obìnrin, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n òṣùwọ̀n ṣékélì. Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí ogún ọdún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ogún ṣékélì fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà márùn-ún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà mẹ́ta fún obìnrin. Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ bá tálákà púpọ̀ dé bi pé kò lè san iye owó náà, kí a mú ẹni náà wá síwájú àlùfáà, àlùfáà yóò sì dá iye owó tí ó lè san lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni náà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́. “ ‘Bí ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ bá jẹ́ ẹranko èyí tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLúWA, irú ẹran bẹ́ẹ̀ tí a bá fi fún OLúWA di mímọ́. Ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà kò gbọdọ̀ pàrọ̀ ẹran mìíràn, yálà kí ó pàrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára tàbí èyí tí kò dára sí èyí tí ó dára. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ti OLúWA ni ẹranko méjèèjì. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ ní ti ẹranko àìmọ́ tí a fi tọrẹ: èyí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà bí i ọrẹ fún OLúWA. Kí ọkùnrin náà mú ọrẹ náà lọ fún àlùfáà. Kí àlùfáà díye lé e, gẹ́gẹ́ bí ó ti dára tàbí bí ó ti bàjẹ́ sí. Iye owó náà ni kí ó jẹ́. Bí ẹni náà bá fẹ́ rà á padà: ó gbọdọ̀ san iye owó rẹ̀ àti ìdá ogún iye owó náà láfikún.
Kà Lefitiku 27
Feti si Lefitiku 27
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Lefitiku 27:1-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò