Lef 27:1-13

Lef 27:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati enia kan ba jẹ́ ẹjẹ́ pataki kan, ki awọn enia na ki o jẹ́ ti OLUWA gẹgẹ bi idiyelé rẹ. Idiyelé rẹ fun ọkunrin yio si jẹ́ lati ẹni ogún ọdún lọ titi di ọgọta ọdún, idiyelé rẹ yio si jẹ́ ãdọta ṣekeli fadakà, gẹgẹ bi ṣekeli ibi mimọ́. Bi on ba si ṣe obinrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ọgbọ̀n ṣekeli. Bi o ba si ṣepe lati ọmọ ọdún marun lọ, titi di ẹni ogún ọdún, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ogún ṣekeli fun ọkunrin, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa. Bi o ba si ṣepe lati ọmọ oṣù kan lọ titi di ọmọ ọdún marun, njẹ ki idiyelé rẹ fun ọkunrin ki o jẹ́ ṣekeli fadakà marun, ati fun obinrin, idiyelé rẹ yio jẹ ṣekeli fadakà mẹta. Bi o ba si ṣe lati ẹni ọgọta ọdún lọ tabi jù bẹ̃ lọ; bi o ba jẹ́ ọkunrin, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ ṣekeli mẹdogun, ati fun obinrin ṣekeli mẹwa. Ṣugbọn bi on ba ṣe talakà jù idiyele lọ, njẹ ki o lọ siwaju alufa, ki alufa ki o diyelé e; gẹgẹ bi agbara ẹniti o jẹ́ ẹjẹ́ na ni ki alufa ki o diyelé e. Bi o ba si ṣepe ẹran ni, ninu eyiti enia mú ọrẹ-ẹbọ tọ̀ OLUWA wá, gbogbo eyiti ẹnikẹni ba múwa ninu irú nkan wọnni fun OLUWA ki o jẹ́ mimọ́. On kò gbọdọ pa a dà, bẹ̃ni kò gbọdọ pàrọ rẹ̀, rere fun buburu, tabi buburu fun rere: bi o ba ṣepe yio pàrọ rẹ̀ rára, ẹran fun ẹran, njẹ on ati ipàrọ rẹ̀ yio si jẹ́ mimọ́. Bi o ba si ṣepe ẹran alaimọ́ kan ni, ninu eyiti nwọn kò mú rubọ si OLUWA, njẹ ki o mú ẹran na wá siwaju alufa: Ki alufa ki o si diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi iwọ alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri. Ṣugbọn bi o ba fẹ́ rà a pada rára, njẹ ki o fi idamarun rẹ̀ kún idiyelé rẹ.

Lef 27:1-13 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA sọ fun Mose pé kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹnìkan bá jẹ́jẹ̀ẹ́ pataki kan láti fi odidi eniyan fún OLUWA, tí kò bá lè mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ, iye tí ó níláti san nìyí: Fún ọkunrin tí ó jẹ́ ẹni ogún ọdún sí ọgọta ọdún, yóo san aadọta ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Ìwọ̀n ṣekeli ibi mímọ́ ni kí wọ́n fi wọn owó náà. Bí ó bá jẹ́ obinrin ni, ẹni náà yóo san ọgbọ̀n ìwọ̀n ṣekeli. Bí ó bá jẹ́ ọkunrin, tí ó jẹ́ ẹni ọdún marun-un sí ogun ọdún, yóo san ogun ìwọ̀n ṣekeli; bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ṣekeli mẹ́wàá. Bí ó bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọmọ ọdún marun-un, tí ó sì jẹ́ ọkunrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka marun-un, bí ó bá jẹ́ obinrin, yóo san ìwọ̀n ṣekeli fadaka mẹta. Bí ẹni náà bá tó ẹni ọgọta ọdún tabi jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ó bá jẹ́ ọkunrin, kí ó san ṣekeli mẹẹdogun, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ obinrin, kí ó san Ṣekeli mẹ́wàá. “Bí ẹni náà bá jẹ́ talaka tóbẹ́ẹ̀ tí kò lè san iye tí ó yẹ kí ó san, mú ẹni tí ó fi jẹ́jẹ̀ẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ alufaa kí alufaa díye lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni tí ó jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí. “Bí ó bá jẹ́ pé ẹran ni eniyan jẹ́jẹ̀ẹ́ láti mú wá, gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sí OLUWA, gbogbo irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tí eniyan bá fún OLUWA jẹ́ mímọ́. Kò gbọdọ̀ fi ohunkohun dípò rẹ̀, tabi kí ó pààrọ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ pààrọ̀ ẹran tí kò dára sí èyí tí ó dára, tabi kí ó pààrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára. Bí ó bá jẹ́ pé ó fẹ́ fi ẹran kan pààrọ̀ ẹran mìíràn, ati èyí tí wọ́n pààrọ̀, ati èyí tí wọ́n fẹ́ fi pààrọ̀ rẹ̀, wọ́n di mímọ́. Bí ó bá jẹ́ ẹran tí kò mọ́ ni, tí eniyan kò lè fi rúbọ sí OLUWA, kí ẹni náà mú ẹran náà tọ alufaa wá, kí alufaa wò ó bóyá ó dára tabi kò dára; iye tí alufaa bá pè é náà ni iye rẹ̀. Ṣugbọn bí ẹni náà bá fẹ́ ra ẹran náà pada, yóo fi ìdámárùn-ún kún iye owó rẹ̀.

Lef 27:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

OLúWA sọ fún Mose pé. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: ‘Bí ẹnìkan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì láti ya ènìyàn kan sọ́tọ̀ fún Ọlọ́run nípa sísan iye tí ó tó, kí iye owó ọkùnrin láti ọmọ ogún ọdún sí ọgọ́ta ọdún jẹ́ àádọ́ta òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà, gẹ́gẹ́ bí òṣùwọ̀n ṣékélì ti ibi mímọ́ OLúWA; Bí ẹni náà bá jẹ obìnrin, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ọgbọ̀n òṣùwọ̀n ṣékélì. Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọdún márùn-ún sí ogún ọdún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ ogún ṣékélì fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ oṣù kan sí ọdún márùn-ún, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà márùn-ún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì fàdákà mẹ́ta fún obìnrin. Bí ẹni náà bá jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí iye owó rẹ̀ jẹ́ òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún fún ọkùnrin àti òṣùwọ̀n ṣékélì mẹ́wàá fún obìnrin. Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ bá tálákà púpọ̀ dé bi pé kò lè san iye owó náà, kí a mú ẹni náà wá síwájú àlùfáà, àlùfáà yóò sì dá iye owó tí ó lè san lé e gẹ́gẹ́ bí agbára ẹni náà tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́. “ ‘Bí ẹ̀jẹ́ tí ó jẹ́ bá jẹ́ ẹranko èyí tí ó jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fún OLúWA, irú ẹran bẹ́ẹ̀ tí a bá fi fún OLúWA di mímọ́. Ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀jẹ́ náà kò gbọdọ̀ pàrọ̀ ẹran mìíràn, yálà kí ó pàrọ̀ èyí tí ó dára sí èyí tí kò dára tàbí èyí tí kò dára sí èyí tí ó dára. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ ti OLúWA ni ẹranko méjèèjì. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ ní ti ẹranko àìmọ́ tí a fi tọrẹ: èyí tí kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà bí i ọrẹ fún OLúWA. Kí ọkùnrin náà mú ọrẹ náà lọ fún àlùfáà. Kí àlùfáà díye lé e, gẹ́gẹ́ bí ó ti dára tàbí bí ó ti bàjẹ́ sí. Iye owó náà ni kí ó jẹ́. Bí ẹni náà bá fẹ́ rà á padà: ó gbọdọ̀ san iye owó rẹ̀ àti ìdá ogún iye owó náà láfikún.