Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí Òkun Tiberia; báyìí ni ó sì farahàn. Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀. Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.
Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jesu dúró létí Òkun: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni.
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní ẹja díẹ̀ bí?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.”
Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin yóò sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.
Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́; wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yín iná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà.
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.” Nítorí náà, Simoni Peteru gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́tàléláádọ́jọ: bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ ṣe?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni.