JOHANU 21:1-12

JOHANU 21:1-12 YCE

Lẹ́yìn èyí, Jesu tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní òkun Tiberiasi. Bí ó ṣe farahàn wọ́n nìyí: Simoni Peteru, ati Tomasi tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) ati Nataniẹli ará Kana, ni ilẹ̀ Galili, ati àwọn ọmọ Sebede ati àwọn meji mìíràn ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà ní ibìkan. Simoni Peteru sọ fún wọn pé, “Mò ń lọ pa ẹja.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa náà yóo bá ọ lọ.” Wọ́n bá jáde lọ, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi. Ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ náà wọn kò rí ẹja kankan pa. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Jesu dúró ní èbúté, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni. Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ọmọde, ǹjẹ́ ẹ ní ohunkohun fún jíjẹ?” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Rárá o!” Ó wí fún wọn pé, “Ẹ ju àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀, ẹ óo rí ẹja pa.” Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, ni wọn kò bá lè fa àwọ̀n mọ́, nítorí ọ̀pọ̀ ẹja. Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń bọ̀ ninu ọkọ̀, nítorí wọn kò jìnnà sí èbúté, wọn kò jù bí ìwọ̀n ọgọrun-un ìgbésẹ̀ lọ. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹja lórí iná eléèédú, wọ́n tún rí burẹdi. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú wá ninu ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa.” Nígbà náà ni Simoni Peteru gòkè, ó fa àwọ̀n sí èbúté. Àwọ̀n náà kún fún ẹja ńláńlá, mẹtalelaadọjọ. Ṣugbọn bí wọ́n ti pọ̀ tó yìí, àwọ̀n náà kò ya. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun.” Kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó bi í pé, “Ta ni ọ́?” Wọ́n mọ̀ pé Oluwa ni.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ