Isaiah 48:17-22

Isaiah 48:17-22 YCB

Èyí ni ohun tí OLúWA wí Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli: “Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ, tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ, tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi, àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò, àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun. Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn, àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán; orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.” Fi Babeli sílẹ̀, sá fún àwọn ará Babeli, ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀ kí o sì kéde rẹ̀. Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé; wí pé, “OLúWA ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.” Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn kọjá nínú aginjù; ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta; ó fọ́ àpáta omi sì tú jáde. “Kò sí àlàáfíà,” ni OLúWA wí, “Fún àwọn ìkà.”