Isaiah 48

48
Israẹli olórí kunkun
1“Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu,
ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹli
tí o sì wá láti ẹ̀ka Juda,
ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ Olúwa
tí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹli
ṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo
2Ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nì
tí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli—
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀:
3Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́,
ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀;
Lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ.
4Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó;
àwọn iṣan ọrùn un yín irin ni wọ́n;
iwájú yín idẹ ni
5Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọ
ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́;
kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yín
tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé,
‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n;
àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.’
6Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn
Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí?
“Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọ
fún ọ nípa nǹkan tuntun,
àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀.
7A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́
ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní.
Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé,
‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’
8Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bí
láti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà.
Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó;
a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ.
9Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;
nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
kí a má ba à ké ọ kúrò.
10Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé
kì í ṣe bí i fàdákà;
Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú.
11Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí
Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.
Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn.
Israẹli dòmìnira
12 “Tẹ́tí sí mi, ìwọ Jakọbu
Israẹli ẹni tí mo pè:
Èmi ni ẹni náà;
Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn.
13Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;
nígbà tí mo pè wọ́n,
gbogbo wọn dìde sókè papọ̀.
14“Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́:
Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí.
Olúwa ti fẹ́ ẹ,
yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni,
apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea.
15Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;
bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.
Èmi yóò mú un wá,
òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀.
16“Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:
“Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;
ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.”
Àti ní àkókò yìí, Olúwa Olódùmarè ni ó ti rán mi,
pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀.
17Èyí ni ohun tí Olúwa
Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli:
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,
tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn.
18Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi,
àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,
àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun.
19Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn,
àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán;
orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúrò
tàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.”
20Fi Babeli sílẹ̀,
sá fún àwọn ará Babeli,
ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀
kí o sì kéde rẹ̀.
Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;
wí pé, “Olúwa ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.”
21Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọn
kọjá nínú aginjù;
ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;
ó fọ́ àpáta
omi sì tú jáde.
22“Kò sí àlàáfíà,” ni Olúwa wí,
“Fún àwọn ìkà.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isaiah 48: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀